Ìjọba Sanwo-Olu ṣe àgbékalẹ̀ ètò adójútòfò ìlera f'áwọn àgbààgbà òṣèré tíátà Yorùbá

Aworan Gomina Sanwo ati awọn agbaagba Oṣere

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu

Gomina ipinlẹ Eko Babajide Sanwo-Olu ti kede eto idojutofo ilera fawọn agbaagba oṣere tiata Yoruba.

O fidi ọrọ yi mulẹ loju opo rẹ ni Facebook nibi ti o ti ṣalaye pe ijọba gbe igbesẹ yi lati ṣeto ti yoo fawọn oṣere yi lanfaani ilera to peye bi wọn ba dagba darugbo.

Asiko apejẹ kan ti o tio gba awọn oṣere tiata Yoruba ni Lagos House Marina si ni eto yi ti waye.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ Gomian Gboyega Akosile naa fi sita tubọ tan imọlẹ si igbesẹ yi ati idi ti Sanwo-Olu fi ṣe agbekalẹ rẹ lasiko yi.

O ni ''Sanwo-Olu yoo san owo idojutofo ilera yi fawọn oṣere tiata ni paapa awọn to n koju ipenija ilera ti ko si si owo ti wọn yoo fi tọju ara wọn.Awọn oṣere yi ti kopa ribiribi ninuidagbasoke ipinlẹ Eko'

Ipenija ilera jẹ ohun ti ọpọ agbaagba oṣere n koju

Ijọba Sanwo-olu ko sọ pato bi wọn yoo ṣe gbe eto yi gba amọ o ni ohun to fọwọ kan ni lẹmi ni pe pupọ awọn oṣere yi lo maa n tọrọ owo lati figbo bukata ilera wọn bi wọn ba ti dagba.

Ko paro lori ọrọ yi nitori loju opo BBC Yoruba gaa n awa naa ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn agbaagba oṣere to koju ipenija ilera ti wọn ko si ri owo fi tọju ara wọn.

Ọrọ yi le debi pe ọkan ninu awọn oṣere yi Foluke Daramola ṣe agbekalẹ ajọ ẹlẹyinjuaanu ti ofi n ṣe iranwọ fawọn oṣere tiata to dagba ti ilera ṣi n dawọn laamu.

Ninu igbiyanju rẹ nigba naa lawọn eeyan ti mọ nipa ipenija to n koju oṣere tiata adẹrinposonu bi Kayode Odumosu tawọn eeyan mọ si Pa Kasumu.

Irufẹ ipenija ilera naa lo ba Babatunde Omidina,Baba Suwe ni igba aye rẹ ki

A nigbagbọ pe Sanwo-Olu yoo mu ileri yi ṣẹ-Ọga Bello

BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn agbaagba oṣere tiata Adebayo Salami to peju sibi apejẹ ti ikede yi ti waye.

A beere lọwọ rẹ pe ṣe kii ṣe ijọba kan fẹ lo asiko oṣelu yi lati fi wa oju rere awọn oṣere lo fi kede eto yi.

Ninu esi rẹ, Adebayo Salami sọ pe oun ni igbagbọ pe ijọba ipinlẹ Eko yoo mu ileri yi ṣe ati pe ohun to dun mọ awọn oṣere agbaagba ni igbesẹ yi jẹ.

''Ijọba yi a maa mu ileri to ba ṣe ṣẹ fawọn araalu. A ni igbagbọ pe eyi ko ni yatọ si tatẹyinwa ninu awọn eto to ṣe fawa oṣere tiata''

O fidi ọrọ mulẹ pe ṣaaju ijọba Sanwo-Olu ṣe agbekalẹ owo iranwọ biliọnu kan Naira fawọn oṣere lasiko Covid-19 ti awọn si ri anfaani ṣe nibi owo yi.

Aworan Adebayo Salami ati Gomina Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu

Aworan Gomina Sanwo ati awọn agbaagba Oṣere

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu