Baba Suwe: Ọmọ olóògbé ní wàhálà tí bàbá òun kojú lọ́wọ́ NDLEA kò tán lára rẹ́ tó fí kú

Ọmọ gbajugbaja apanilẹrin osere tiata to di oloogbe, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe, ti tu kẹkẹ ọrọ silẹ nipa iriri baba rẹ lọwọ ajọ to n gbogun ti oogun oloro ni Naijiria, NDLEA.
Omidina Adebowale Junior, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn nnkan ti ko le gbagbe nipa baba rẹ, salaye pe oun ati baba oun maa n ja pupọ, eyi yoo si jẹ ki oun saaro rẹ pupọ.
O ni arẹmaja ko si, ajamarẹ ni ko sunwọn amọ kii pe isẹju marun ti awọn yoo fi pari rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Wo nǹkan mẹ́jọ tí o lè má mọ̀ nípa Baba Suwe tó dolóògbé
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Jàndùkú kọlù mi, gé mi lára bíi olè torí mo jẹ́rìí tako ìjọba níbi ìwádìí ìpànìyàn Endsars Lekki''
- Femi Fani-Kayode ṣàlàyé bí ìrìnàjò rẹ̀ sọ́dọ̀ EFCC ṣe jẹ́
- Ẹ lọ san ₦20bn owó ìtanràn fún Sunday Igboho títí January - Iléejọ́ fọnmú fún DSS
- Kò sí ìfẹ̀míṣòfò kankan ní Lekki Too Gate, àlọ́ àpamọ̀ lásán ni èsì ìgbìmọ̀ EndSARS - Lai Mohammed
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
O fikun pe awọn mejeeji mọ ọwọ ara awọn, to si n gba oun nimọran lati tẹsiwaju ninu isẹ agbabọọlu ti oun n se.
Adebowale ni alawada ninu ile ni baba oun, bo si se n se ninu sinima naa lo n se loju aye, to si han gbangba pe lati ọrun lo ti mu ẹbun awada wa.
Wahala ajọ NDLEA wa lara oun to tete pa Baba mi:
Adebowale Omidina, lasiko to n salaye ohun to se okunfa iku baba rẹ ni, wahala ti baba oun koju lọwọ NDLEA jẹ eleyi ti ọgbẹ rẹ ko tan lọkan baba Suwe titi to fi jade laye.
Adebowale sọ pe oun ko le sọ pàtó boya wahala NDLEA yii lo fa aarẹ sara Baba Suwe ṣugbọn nkan ko jọra mọ lati igba naa fún idile awọn.
Bẹẹ ba gbagbe, lọdun 2011 ni ajọ NDLEA fi ẹsun kan Baba Suwe pe o gbe oogun oloro amọ lẹyìn iwadii wọn, ko fi ẹri to daju mulẹ nile ẹjọ lori ẹsun pe lootọ ni Baba Suwe gbe oogun oloro.
Idi si ree ti ile ẹjọ fi da Baba Suwe silẹ, to si ni ki ajọ to n dena gbigbe oogun oloro naa fun ni miliọnu mẹẹdọgbọn naira owo gba ma binu amọ ko ri owo naa gba titi to fi ku.
Baba Suwe sọ pe iriri oun ni ahamọ ajọ NDLEA naa, ni ko jẹ ki oun le rin daada mọ lẹyin ti oun jade ni ahamọ wọn.
Ni kete to si kuro ni ahamọ, tileẹjọ da lare, ni Baba Suwe bẹrẹ aisan ọlọjọ pipẹ, koda, wọn gbe lọ soke okun fun itọju ni asiko kan amọ ko si fi bẹẹ gbadun, titi ti ọlọjọ fi de ba a.
Mo tọrọ aforijin lọwọ awọn ẹbi wa lori ọrọ ti mo sọ ninu fidio ti mo gbe jade:
Adebowale Omidina, ni kete ti baba rẹ di oloogbe, lo ti fẹsun kan awọn mọlẹbi ninu fónrán fidio kan tó gbòde kan pe, wọn pa baba rẹ ti, lai setọju rẹ titi to fi ku.
Fidio mejeeji ti Adebowale ju sori ayelujara naa lo fa awuyewuye laarin ẹbi, koda, awọn ẹgbẹ osere tiata gan fara ya lori rẹ.
Amọ Adebowale, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, ti wa tọrọ aforijin lọwọ ẹbi atawọn alajọsisẹpọ baba rẹ, ti fidio naa tabuku wọn.
Adebowale salaye pe iku baba oun lo ba oun lojiji, itara naa si ni oun fi se fidio naa lai lero pe o le ru ọkan eeyan kankan soke.
"Mo tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan ti fidio ti mo se, nibi ti mo ti gbe oku baba mi sita ba tabuku wọn, ẹ ma binu, ọmọde lo n se mi.
Itara iku baba mi lo mu mi kede pe ko si ẹnikan, oju opo Whatsapp mi si ni mo gbe fidio naa si, amọ bo se wa gbalẹ kan kaakiri awọn oju opo ayelujara ni ko ye mi rara.
Igba ikẹyin Baba Suwe:
Adebowale ni igbakigba ti oun ba fi fidio ibi ti baba mi ti n ṣe ere tiata han, inu rẹ maa n dun, ti yoo si maa beere pe ṣe awọn yoo sí tun ṣe ere tiata pada mọ?
"Igba mii wọn a bù s'ẹkun, igba mi wọn a sì maa rẹrin, sugbọn mo máa n fi wọn lọkan balẹ pe wọn yoo tun pada máa ṣe ere tiata"
O ni nise ni baba Suwe a máa ronu pupọ nipa iyawo rẹ ati awọn ọmọ naa.
O ni koda laipẹ yii lọ sọ fún àwọn pe oun ko lero pe oun ni asiko púpọ lati lo pẹlu awọn mọ





















