A ti ṣetán láti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì táa gùnlé - ASUU

Ìpàdé ASUU pẹ̀lú Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Nàìjíríà, ASUU, Ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuel Osodeke ti ní láìpẹ́ ọjọ́ ni ASUU máa fi òpin sí ìyanṣẹ́lódì tí ẹgbẹ́ náà gùnlé.

Osodeke sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin sọ̀rọ̀ ní ìlú Abuja lọ́jọ́ Ajé ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹwàá, ọdún 2022.

Ó ní pẹ̀lú ìpàdé tí àwọn ṣe pẹ̀lú àwọn adarí ilé náà, ó fihàn wí pé dídùn ni ọsàn maa so fún àwọn àti wí pé àwọn ní ìgbàgbọ́ wí pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yó da àwọn láàmú mọ́.

Ó fi kún un pé bí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ṣe ti bá àwọn dá sí ọ̀rọ̀ náà, àwọn nígbàgbọ́ pé ohun gbogbo yóò ní ìyanjú pàápàá nítorí ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ti wà nílé fún ọjọ́ pípẹ́.

Osodeke ṣàlàyé pé gbogbo nǹkan ti àwọn ń jà fún kìí ṣe fún ti ara àwọn nìkan bíkòṣe láti mú kí ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà le gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀.

Ó tẹ̀síwájú pé ohun tí àwọn ń fẹ́ ni kí ìjọba máa ṣẹ̀tọ́ tó péye kí wọ́n sì máa fún àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ní owó tó tówó gẹ́gẹ́ bí owó oṣù kí àwọn olùkọ́ nílẹ̀ òkèrè le máa gbìyànjú láti fẹ́ wá sí Nàìjíríà wá ṣiṣẹ́.

“Owó ilẹ̀ òkèrè ló yẹ kí ìjọba ma fi san owó owó fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì láti le fajú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ilẹ̀ òkèrè mọ́ra.”

Bákan náà ló kọminú lórí bí àwọn olùkọ́ ṣe ń fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti wá iṣẹ́ lọ sí ilẹ̀ òkèrè tó sí nì àkóbá ńlá ni yóò jẹ́ fún ètó ẹ̀kọ́.

Osodeke ní ìrètí wà wí pé láìpẹ́ ọjọ́ ni àwọn máa fi òpin sí bí àwọn ṣe ń wo iṣẹ́ níran.

Nígbà tó dúpẹ́ lọ́wọ́ abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila fun ipa tí ilé kó lórí ọ̀rọ̀ náà, ó ní òun ní ìgbàgbọ́ wí pé tó bá jẹ́ wí pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin bá àwọn dá sí ọ̀rọ̀ náà látilẹ̀ ni òun gbàgbọ́ pé ìyanṣẹ́lódì náà kò ní ju ọ̀sẹ̀ méjì lọ.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila ní ìpàdé tí àwọn bá ASUU ṣe so èso rere.

Gbajabiamila ní àwọn tún ti bá ìjọba àpapọ̀ ṣe ìpàdé lórí gbogbo ìbéèrè ASUU tí àwọn sì ti fẹnukò lórí ìpinnu kan.

Ó ní ìjọba àpapọ̀ yóò ìpinnu wọn léde lónìí àti pé ilé ti gbìyànjú láti ri pé gbogbo nǹkan tí ASUU ń bèèrè fún ni ìjọba àpaps múṣe.

Ó fi kun pé owó bílíọ̀nù 470 náírà ni ìjọba àpapọ̀ yà fún ASUU nínú àbá ìsúná 2023 láti fi mójútó gbogbo ohun tí ASUU ń bèèrè fún.

Ó ni òun gbàgbọ́ pé láìpẹ́ ni ASUU ma fòpin sí ìyanṣẹ́lódì náà nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń jẹ ìyà ìyanṣẹ́lódì náà.

Ẹ rántí pé láti ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kejì ọdún 2022 ni ASUU ti bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì tó sì ti ń pé oṣù mkjọ ló báyìí.