Igbẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke kọ̀ láti wáyé lónì, ohun tí wọ́n sọ fáwọn Akọ̀ròyìn rèé

Oríṣun àwòrán, Google
Igbẹjọ lori iku Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo to padanu emi rẹ ninu ọdun to kọja ko waye loni niluu Osogbo.
Ọjọ kẹwaa oṣu kẹwaa ni Adajọ Adepele Ojo sun Igbẹjọ naa si sugbọn ko waye lana nítorí pe o jẹ ọjọ ìsinmi lẹnu lati ṣe ajọyọ ọdun ibi ojisẹ Ọlọrun.
Iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ ni pe ileẹjọ giga ipinle Osun ti sun Igbẹjọ naa siwaju.
Agbẹjọro fun awọn olupẹjọ iyẹn idile oloogbe Timothy Adegoke, Fatima Adeshina lo fi ọrọ naa mulẹ lẹyin ti ikọ ileeṣẹ BBC News Yoruba balẹ si ileẹjọ ninu Osogbo.
O ni lẹyin ti ileẹjọ fẹnu ko lati tẹsiwaju ni ọjọ kẹwaa oṣu kẹwaa to bọ si ọjọ ìsinmi lẹnu isẹ eyi ni ko fun wọn ni anfani lati joko lana.
Ọsẹ to kọja ni Adajọ Adepele Ojo sun Igbẹjọ lori ìlera ọkan lara awọn afurasi meje to jẹjọ lori iku Timothy Adegoke, Rahmon Adedoyin sìwaju lẹyin ti awọn Agbẹjọro bere fun anfani fun un lati lọ gba itọju ni ile iwosan.











