Bí àwọn adarí ASUU ṣe le wa danù, táa di ọmọ òrukàn lọ́dún 2013 rèé - Alága CONUA bá BBC sọ̀rọ̀

Àkọlé fídíò, ASUU Vs CONUA: Niyi Sumonu to gba àdé adarí CONUA sọ bí àwọn adarí ASUU ṣe yan àwọn kan jẹ

Ko jẹ ajoji mọ pe ijọba apapọ ti ṣẹ ẹgbẹ apapọ awọn olukọ fasiti ti gbogbo agbaye mọ tẹlẹ ni Naijiria leegun ẹyin pẹlu fifi ontẹ jan ẹgbẹ tuntun fun awọn olukọ fasiti.

O ṣalaye pe iwasaye ẹgbẹ Congress of Nigerian Universities, CONUA ṣẹlẹ latari nkankan to waye lọdun 2013 nigba ti gbogbo awọn ṣi jọ wa labẹ asia ẹgbẹ ASUU.

"Awọn ohun to ṣẹlẹ yẹn, awọn olori ajọ ASUU ṣe awọn ẹsun aṣemaṣe ti a si fi ẹsun kan wọn nigba naa".

CONUA

O ṣalaye pe awọn ẹsun naa da lori ilan iṣiṣẹ wọn ati bi wọn ṣe n ṣe ofin ẹgbẹ. O tun jẹ ko di mimọ pe nigba naa, gbogbo ọmọ ẹgbẹ pata lo laṣẹ lati di adari ṣugbọn awọn adari awọn bẹrẹ si ni pọn sẹyin awọn kan.

O ni kaka ki wọn wa atunṣe, ṣe ni wọn le awọn kan lọ sile ti wọn si sọ awọn ti ọmọ orukan. Awọn ọmọ orukan yii lo korajọ lọdun 2018 ti wọn si kọwe si ijọba amọ ti ko tii si esi.

Eyi ni ijọba ri bii anfani nigba ti wọn gbọ ẹjọ wọn ninu oṣu kẹwa ti wọn si kuku wa fi ontẹ jan CONUA lọjọ kẹrin oṣu kẹwa ọdun 2022.