Wo àwọn ànfàání tí ìlú yóò jẹ lára 'Airport' tí Eko gba àṣẹ láti kọ́ sí Lekki

Sanwo-Olu ati Hadi Sirika

Oríṣun àwòrán, Lagos state government

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ri iwe aṣẹ gba lati kọ papakọ ofurufu si agbegbe Lekki ni ipinlẹ naa.

Nibi ipade apero ọrọ aje kan, Ehingbeti Lagos Economic summit, to waye nipinlẹ Eko, ni minisita Naijiria fun irinajo oju ofurufu, Hadi Sirika, ti fun Gomina ni iwe aṣẹ naa.

Sirika sọ pe papakọ ofurufu naa yoo so Naijiria pọ mọ awọn orilẹ-ede agbaye , ti yoo si tun ṣi ilẹkun ibaṣepọ ọrọ aje silẹ fun ipinlẹ Eko.

Minisita naa sọ pe papakọ tuntun naa yoo mu adinku ba bi eero to n lo papakọ Murtala Muhammed ṣe ma n pọ ju.

Bakan naa lo sọ pe ipinlẹ Eko ni gbogbo nkan to mu ko nilo papakọ ofurufu mii.

Ọjọ diẹ sẹyin ni oludamọran fun Gomina Sanwo-Olu lori ajọṣepọ ijọba ati awọn ileeṣẹ aladani, Ope George, sọ pe ọdun 2023 ni ireti wa pe kikọ papakọ naa yoo bẹrẹ.

O ni ori ẹgbẹrun mẹta aabọ eeka ilẹ ni wọn o kọ papakọ ọkọ ofurufu naa si ni agbegbe Lekki.

Bakan naa ni Ọgbẹni George sọ pe gbogbo eto bi papakọ naa yoo ṣe ri, ati awọn ilana irinajo ofurufu ti wa nilẹ.

“Ijiroro si ti n waye lori ọba ti ao gba ri owo fun kikọ rẹ pẹlu ati awọn nkan mii.”

Ireti wa pe ko ni i din ni miliọnu marun-un eeyan ti yoo ma a lo papakọ ọkọ ofurufu naa ni ọdọọdun.

Ninu ọrọ tiẹ naa, Gomina Sanwo-Olu sọ pe pẹlu ajọṣepọ ijọba apapọ ni awọn pinnu iṣẹ akanṣe naa.

Pẹlu ajọṣepọ awọn oludokowo nile ati nilẹ okeere si ni wọn fẹ kọ papakọ ọkọ ofurufu tuntun naa.

Anfaani wo ni ijọba sọ pe ilu yoo jẹ lara papakọ ọkọ ofurufu naa?

  • Ijọba ni yoo mu ko rọrun fun awọn ileeṣẹ ati awọn olokoowo mii to wa ni agbegbe ilu tuntun, Lekki Free zone, lati ma a ko ọja wọn lọ silẹ okeere
  • Bakan naa ni ijọba sọ pe adinku yoo ba asiko ti awọn fi n rinrinajo
  • O ni fun anfaani awọn olokoowo ni awọn ṣe fẹ kọ, lati mu ki iṣẹ wọn ko rọrun