Ìpolongo ìdìbò bẹ̀rẹ̀, ohun tí BBC wú jáde tẹ́ẹ gbúdọ̀ mọ̀ rèé
Gẹgẹ bi awọn ẹgbẹ oṣelu Naijiria ṣe ti gberasọ pẹlu ipolongo idibo kaakiri awọn ipinlẹ ati ilu orilẹede Naijria, eto Laa Han Mi wa ti ọsẹ yii lori BBC Yoruba ti jade.
Eto ti ọsẹ yii da lori awọn nkan ti yoo ṣẹlẹ lasiko yii to si yẹ ki awọn araalu reti latọdọ awọn ẹgbẹ oṣelu kọọkan ati oludije wọn fun ipo aarẹ.
O ni awọn nkan ti oludije gbọdọ tẹle labẹ ofin bẹẹ naa si ni ẹyin araalu naa ni ojuṣe ati ẹtọ. Lara awọn nkan ti ẹ o mọ ninu fidio yii ni:
Ilana ajọ eleto idibo INEC, akọsilẹ eto ti awọn oloṣelu ni fun yin ati gbogbo pọpọṣinṣin ti yoo ṣẹlẹ. Akọroyin BBC Yoruba, Ahmad Ambali yoo muu yin rinrinajo yii ẹ o si gbadun rẹ.












