Ọba tó lu ọkùnrin alásè fọ́ lójú torí ó bá Olorì jó lójú agbo fojú ba ilé ẹjọ́

Ọba Nureni ati Wasiu Oduwole

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ile ẹjọ kan ni ipinlẹ Ogun ti gbọ ẹjọ laarin Ọba alaye kan, Oba Nureni Oduwaye ati ontaja Wasiu Oduwole fun ẹsun pe Ọba naa lu Wasiu titi ti oju rẹ fi fọ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi eeyan kan ni ile itura Moore Blessing ni agbegbe Sagamu.

Iroyin sọ pe ṣe ni Ọba naa hu iwa yii nigba ti oun ati iyawo rẹ lọ ṣe ibẹwo si ile itura kan ti arabinrin to n jẹ Iya Alaje ti n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi.

Ọba Nureni fi ẹsun kan ontaja naa, Wasiu Oduwole ti wọn pe ko wa se ọbẹ ẹja alata yẹriyẹri fun inawo naa pe o n ba iyawo oun jo loju agbo.

́Bakan naa ni iroyin kan tun sọ pe Wasiu wa ni ẹgbẹ elere DJ ti wọn pe to si n ‘salaye fun ẹni to ni ile itura naa nipa ọbẹ ẹja to se wa lo ba taju kan ri arẹwa obinrin kan to n jo si gbẹdu orin ti wọn n kọ loun naa ba pakuru mọ obinrin naa to si n baa jo ayafi to ri bii ala loju nigba ti Ọba sunmọ wọn to si n bere pe ta lawọn?

Ki ni Ọba ṣe loju agbo?

Wọn ni Ọba naa fi ibinu kuro to si lọ sinu ọkọ rẹ. Nigba naa lawọn eeyan sọ fun Wasiu pe ko tete lọ dọbalẹ lati maa bẹ Ọba fun ẹṣẹ to ṣẹ.

“Nibi to ti dọbalẹ to n bẹ Ọba naa ni Ọba Nureni ti fi ibinu ju u ni ẹṣẹ akọ loju. Wọn gbe e digba digba lọ ileewosan bẹẹ si ni wọn lọ fi ẹjọ ohun to ṣẹlẹ sun ni agọ ọlọpaa”.

Nibayii, Ọba Nureni Oduwaye ti foju ba ile ẹjọ to wa ni Sagamu, ipinlẹ Ogun fun ẹsun pe o fọ ontaja, Wasiu loju.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ọlọpaa, ẹsun meji ni wọn fi kan Ọba Nureni to da lori pipa eeyan lara gidi gan ati dida omi alafia ilu ru.

Ẹsun naa ka wipe: “Iwọ Ọba Nureni Oduwaye ni ọjọ Kọkanlelogun Oṣu Kẹsan ni nkan bii ago mẹwa abọ alẹ ni ile itura Moore, Opopona Shagamu/Ikene ṣe ohun to lodi si ofin nipa ṣiṣe ipalara fun Wasiu Oduwole nipa fifi bata ẹsẹ rẹ gbaa loju eyi to jẹ ko fara pa ni oju apa osi rẹ to si sọọ di afọju ni oju naa.

Si eyi, o lodi si abala ofin 335 ti ipinlẹ Ogun ọdun 2006, ijiya si wa fun un labẹ ofin.”