Dangote dáa padà fún ìjọba Kogi bó ṣe ti iléèṣẹ́ 'Dangote cement' pa ní Obajana

Dangote ati Gomina Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ simẹnti Dangote ti sọ pe lati ọdun 2002, ni oun ti ni ipin idokowo ileeṣẹ simẹnti Obajana, to wa nipinlẹ Kogi.

O ni lasiko ti oun dokowo, ijọba to da ileeṣẹ naa silẹ ko tii bẹrẹ si ni ṣe ohunkohun.

Awọn alaṣẹ Dangote sọ pe obitibi owo ni awọn ti fi dokoowo si ileeṣẹ simẹnti naa, ti oun si tẹle gbogbo ilana to yẹ ki oun to bẹrẹ ọrọ aje nipinlẹ Kogi.

Ọrọ ti ileeṣẹ Dangote sọ yii waye lẹyin ti ijọba ipinlẹ Kogi, ti ileeṣẹ naa pa nitori ẹsun pe ọna alumọkọrọyi lo gba ra awọn ipin idokowo rẹ nibẹ.

Ṣugbọn ileeṣẹ yii sọ pe gbogbo igba ni oun n ṣe ojuṣe oun nipa sisan ọpọlọpọ biliọnu Naira ni owo ori, ati titun awọn ilu to wa ni ayika ileeṣẹ naa ṣe.

Ọga ileeṣẹ simẹnti Dangote naa, Alhaji Sada Ladan Baki sọ fun BBC pe , ijọba lo ranṣẹ pe awọn lati dokowo nileeṣẹ naa, awọn si ṣe bẹẹ.

O ni “gbogbo ilana ati ẹtọ to yẹ ka ṣe lati muṣẹ, to fi mọ gbogbo nkan to rọ mọ didokoowo sileeṣẹ naa.

“Ṣugbọn a ko mọ idi ti ijọba ipinlẹ Kogi fi gbe igbesẹ lati ti ileeṣẹ naa pa, nitori wọn fura si wa pe magomago wa ninu ba a ṣe ni idokowo sileeṣẹ naa.”

Alhaji Ladan Baki ni o ti le ni billiọnu mẹrindinlogun Naira ti awọn ti san ni owo ori, lati igba ti Gomina Yahaya Bello ti de ipo.

Ọsẹ to kọja ni ile aṣofin ipinlẹ Kogi ti ileeṣẹ naa pa, pẹlu awijare pe awọn ri iwe ẹsun gba lati ọdọ awọn ilu kan, pe ileeṣẹ Dangote ko tẹle awọn ilana to yẹ nigba to ra ipin idokoowo ileeṣẹ simẹnti Obajana.

Idi si niyii ti awọn alaṣẹ fi sọ pe ki ileeṣẹ naa ko awọn ẹri bo ṣe gba ileeṣẹ naa wa.

Akọwe ikede fun ijọba ipinlẹ Kogi, Mohammed Onogu, sọ pe lati bi ọdun marun-un ni ijọba ti n gbiyanju lati ṣe ipade pẹlu awọn alaṣẹ Dangote, ti oun si tun yan oriṣiriṣi igbimọ lati ṣe agbeyẹwo ilana ti Dangote fi gba ileeṣẹ naa, ati ìdá mẹwaa ipin to jẹ ti ijọba ipinlẹ Kogi.

O ni ṣugbọn ileeṣẹ naa kọ lati ko ẹri ranṣẹ.

Ọgbẹni Onogu sọ pe awọn aṣoju ileeṣẹ Dangote sọ nibi ipade ti wọn ba ijọba ṣe nigba naa pe awọn yoo ko awọn iwe akọsilẹ ati ẹri wa, ṣugbọn ko ṣe bẹẹ, bẹẹ ni ko ba ijọba sọ ohunkohun titi di igba ti ile aṣofin ti ileeṣẹ naa pa.

Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Gomina Yayaha Bello sọ pe oun yoo gba ogun ibi awọn eniyan ipinlẹ Kogi fun wọn lọwọ ẹnikẹni botiwu ko l'agbara to

Awọn figilante ijọba Kogi pa awọn oṣiṣẹ wa lara - Dangote

Awọn alaṣẹ Dangote sọ pe eero to yabo ileeṣẹ naa to ẹẹdẹgbẹta, ti wọn si dana sun awọn ọkọ simẹnti, wọn ba awọn kan jẹ, wọn si tun ja awọn bọọsi to jẹ ti ileeṣẹ naa gba.

Wọn ni niṣe ni awọn fijilante ijọba to wa ti ileeṣẹ naa pa, yinbọn mọ awọn oṣiṣẹ kan, ti wọn si tun gbakoso awọn ọfiisi.

Bakan naa ni ileeṣẹ naa sọ pe ko din ni oṣiṣẹ mẹtadinlọgbọn to farapa lasiko ikọlu naa.

Orisun wahala to n koju ileeṣẹ simẹnti Dangote

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ijọba ipinlẹ Kogi fin ẹsun kan pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ Dangote ti sọ ileeṣẹ simẹnti Obajana di ti Dangote, botilẹ jẹ pe adehun to wa laarin rẹ ati ijọba ni pe wọn jọ ni i ni.

Kọmisanna fun eto iroyin nipinlẹ naa, Kingsley Fanwo sọ pe irọ patapata ni ileeṣẹ Dangote n pa pe ijọba ta Obajana fun oun.

O ni igbimọ oluwadii ti ijọba gbe kalẹ ti gba ijọba niyanju lati wọgile iwe ilẹ meje to fun Dangote.

Bakan naa ni akọwe ijọba ipinlẹ Kogi sọ pe ijọba ni ẹri lati fihan pe oun ko fi igba kankan ta Obajana Cement fun Dangote.

Ọgbẹni Fanwo sọ pe ijọba lo ni awọn iwe ti Dangote fi ya biliọnu mẹtalelọgọta lati kọ ileeṣẹ simẹnti naa.

O ni amọ, ko fi igba kankan fun ijọba ni ipin tiẹ lara ere to n wọle lati igba ti ileeṣẹ naa ti bẹrẹ iṣẹ.

O ni gbogbo ọna ni ijọba Kogi yoo fi gba ogun ibi awọn eeyan ipinlẹ naa fun wọn lọwọ ẹnikẹni, botiwu ki ẹni naa ga tabi mọ eeyan to.

Bakan naa lo sọ pe awọn yoo gba gbogbo owo ori ati ere ti Dangote kọ̀ lati fun ijọba lati ọdun 2002 to ti n lo ileeṣẹ naa.

Iwọde waye nilu Abuja lori ọrọ naa

Ẹgbẹ kan, Mass Action Against Corruption, sẹ iwọde nilu Abuja ni ọjọ Iṣẹgun.

Ẹgbẹ naa fi ẹsun kan pe ileeṣẹ Dangote n lo ọrọ aje ipinlẹ Kogi fun anfaani ara rẹ

Agbẹnusọ wọn, Cecilia Ikechukwu sọ fun awọn akọroyin pe Alhaji Aliko Dangote, fi ọgbọn jibiti gba ileeṣẹ simẹnti Obajana , lai si ẹri pe o san owo fun ìdá aadọrun (90%) to ra lọwọ ijọba ipinlẹ Kogi.

Ijọba apapọ ti dasi ọrọ naa

Lọwọlọwọ, ijọba apapọ ti dasi ọrọ naa pẹlu erongba lati pẹtu si igun mejeeji ninu.

Amọ Gomina Yahaya Bello sọ pe oun ṣetan lati ni agbọye pẹlu awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ti wọn ba wa fun ipade.

Amọ awọn alaṣẹ Dangote ni awọn ko ni i yi ọrọ awọn pada pe Dangote lo ni ileeṣẹ simẹnti Obajana.