Arẹwà míì, Ronke Ademiluyi tún di Ayaba fún Ooni Ife

Oríṣun àwòrán, Queen Móremí Àjàsorò International
Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti ṣe igbeyawo pẹlu olori oloti tuntun mii, eyii tii ṣe iyawo karun un ti yoo fẹ lẹnu lọọ yii.
Orukọ olori tuntun naa ni Ronke Ademuluyi, ilu Ile Ife nipinlẹ Osun si ni igbeyawo alarede naa ti waye lọjọbọ.
Gẹgẹ bo ṣe waye lawọn igbeyawo ti Ooni ti ṣe sẹyin, ko si nibi ayẹyẹ igbeyawo naa, amọ awọn oloye rẹ, to fi mọ ẹṣọ aafin ati ọpa aṣẹ rẹ yọju sibẹ.
Olori tuntun ọhun, to jẹ gbajumọ oniṣowo sọ pe oun ati Ooni ti mọ ara awọn lati ọdun 2015 ṣaaju igbeyawo yii.
Ṣaaju lawọn iroyin kan ti kọkọ sọ pe ọdun 2016 ni Olori tuntun naa ati Ooni yoo gbeyawo, amọ igbeyawo ọhun ko waye lọdun naa lọhun.
Ta ni Olori Ronke Ademuluyi?
- Idile ọba ni wọn bi Ronke Ademiluyi si ni Ile Ife
- Oun ni arọmọdọmọ Ooni Ajagun Ademiluyi to ti rewalẹ aṣa
- O lo ibẹrẹ aye rẹ ni Naijiria ko to tẹkọ leti lọ silẹ Gẹẹsi
- Ademiluyi kẹkọ gboye nipa imọ ofin ni fasiti Thames Valley niluu London
- Oun ni oludasilẹ ati olootu eto Africa Fashion Week to maa n waye lọdọdun niluu London, nibi ti wọn ti maa n ṣe igbelarugẹ aṣọ ati aṣa ilẹ adulawọ
- Ademiluyi lo wa nidi eto ‘Queen Moremi,’ oun naa tun ni oludasilẹ ileesẹ Adire Oodua
Ti ẹ ko ba gbabe, ọsẹ to kọja yii ni Ooni gbe Ashley Adegoke niyawo, iyẹn lẹyin to ti kọkọ fẹ Tobi Philips ati Mariam Anako ṣaaju.











