Ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti sú mi! Nkan tí màá ṣe nìyíì- Adájọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Adajọ ileẹjọ giga ipinle Osun, Adepele Ojo ti bu ẹnu atẹlu bi awọn Agbẹjọro ṣe n fi ìgbẹjọ lori iku akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo Timothy Adegoke lẹyin ti ọkan lara awọn afurasi, Dokita Rahmon Adedoyin ko lati yọju si ileẹjọ.
Onidajọ Ojo ni o tapa sì ofin lẹyin ti oun ti ṣe ileri fun awọn araalu pe igbẹjọ ko ni ju oṣu mẹfa sugbọn o ti ń ju bẹ lọ, tí ko si dun mọ oun nínu rara.
"Mo ṣetan lati gbe ẹjọ yii fun Adajọ torí o ṣe ọpọlọpọ idaduro fun mi.
"Nkan méjì ni fifalẹ yii le mu jade, boya kí n gbe fun adajọ mìíran to ni ọpọlọpọ ọdun lẹnu isẹ tabi ki n ni kí awọn afurasi ma gba ile wọn wa a jẹjọ.
"Mo ní láti wa lati ilẹ Amerika nitori ẹjọ yii."
Adedoyin kó yọjú sí ilé Ẹjọ́ lónì
Oludasile ile ìtura àti ọkan lara awọn afurasi meje to jẹjọ lori iku Timothy Adegoke, Dokita Rahmon Adedoyin ko si lara awon afurasi to yọju sì ileẹjọ loni ni ileẹjọ giga ipinle Osun.
Dokita Rahmon Adedoyin ni ó kọwe, to beere fun anfaani lati gba itọju lẹyin ti kudiẹkudiẹ de ba ilera rẹ ni ogba ẹwọn.
Adajọ sọ pe Rahmon Adedoyin ni lati wa ni ileẹjọ nítorí oun lo waju awọn afurasi naa ninu ẹsun tí wọn fi kan wọn.
Agbẹjọro Ita Okon bu ẹnu atẹlu bi Dokita Rahmon Adedoyin ko ṣe wa si ileẹjọ lẹyin ọpọlọpọ oṣu tí wọn fi oju sọna fun idajọ òdodo.
Agbẹjọro awọn olupẹjọ, Fatima Adeshina, Agbẹjọro to duro fun agbẹjọro àgbà, Femi Falana ni owurọ ni osisẹ ọgba ẹwon kesi oun nípa ìlera ọkan lara awọn afurasi, eyiun Rahmon Adedoyin.
Ní bayi, Adajọ Adepele Ojo wa sun igbẹjọ naa si ọjọ keje ati kẹjọ oṣu Kọkanla.
Adajo Ojo ni igba ikẹyin re ti oun yoo fi anfani fun awọn agbẹjọro làti ṣe idaduro fun idajọ naa.












