Ó ṣeéṣe kí ẹkun omi gba Ikoyi, Lekki, Victoria Island, àtàwọn agbègbè míì – Ìjọba Eko kìlọ̀

3rd Mainland Bridge

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Opin ọsẹ to kọja yii ni fidio kan bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara nipa bi omi to wa labẹ afara Third Mainland, niluu Eko ṣe n ga sii.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ naa ni ki awọn araalu ma naani fidio naa, ati pe ki wọn maṣe foya, ibẹrubojo ti bẹrẹ si n ba awọn eeyan kan nipinlẹ ọhun nitori ẹkun omi to le waye nibẹ.

Ninu fidio naa ni a ti ri bi omi ọhun ṣe kun si lagbegbe Oworonsoki si abẹ afara Third Mainland naa.

Amọ kọmiṣọna to n ri si ọrọ ayika nipinlẹ Eko, Tunji Bello ni agbegbe Oworonsoki nikan ni omi naa ti kun, awọn eeyan ko si gbọdọ fi agbegbe naa nikan ṣapejuwe ohun to n ṣẹlẹ ni gbogbo omi to wa labẹ afara naa.

O ṣeeṣe ki ẹkun omi gba Ikoyi, Lekki ati Victoria Island

IKoyi, Lagos

Bello ni “Agbegbe ti awọn olowo n gbe ni Ikoyi, Lekki ati Victoria Island, to fi mọ awọn to n gbe lẹba eti omi ni Epe ati Badagry gbọdọ sọra gidi nitori ikun omi to le waye nibẹ.”

Kọmiṣọna naa, ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ rẹ fi sọwọ si BBC sọ pe awọn eeyan ọhun ni lati wa ni imurasilẹ nitori omi to n kun si niluu Eko.

O ni bi omi ọhun ṣe n pọ si ti mu ko ṣoro fun awọn omi to n ṣan lọ sinu ọsa ma ri aye wọle mọ, eyii to le mu ki awọn omi naa ṣan si aarin ilu.

O ni “Eyii le mu ki omi gba gbogbo aarin adugbo ati oju popo titi ti omi inu okun naa yoo fi lọ silẹ.”

Flooding

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹkun omi to le waye ni gbogbo Eko

Ijọba ipinlẹ tun kilọ fun awọn eeyan ipinlẹ naa lati dẹkun ati maa fi awọn atẹjade tabi fidio to le mu ipaya ba awọn eeyan nipa ẹkun omi to le waye loju opo wọn lori ayelujara.

Ẹwẹ, Bello ti ni ki wọn wa ni imurasilẹ nigbakugba ti ojo ba n rọ, ki wọn si dẹkun ati maa da idọti sinu agbara ojo.

Lara awọn agbegbe ti wọn ni ẹku omi naa le gba ni Ketu, Alapere, Agric, Owode Onirin, Ajegunle, Alagbole, Kara, Isheri Olowora, Araromi, Otun Orisha community, Agiliti, Maidan, Mile 12, ati Odo Ogun.

Awọn agbegbe to ku ni Owode Elede, Agboyi kinni, Agboyi keji, ati Agboyi kẹta.

Ohun to yẹ ki o ṣe ti omi ba gba ile tabi adugbo rẹ

Flooding

Oríṣun àwòrán, CLARKSON IPKO DIRI

Ti ẹkun omi ba gba ile tabi adugbo rẹ, ohun akọkọ to yẹ ki o ṣe ni ki o pe nọmba ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, NEMA.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa ni Naijiria, Manzo Ezekiel, sọ fun BBC pe awọn araalu le ke pe awọn ni gbogbo igba.

Nọmba ipe pajawiri NEMA ni 0800 tabi 0800 2255 6362.