Ọwọ́ EFCC tẹ èèyàn mẹ́ta tí wọ́n ta ìbò lásìkò ètò ìdìbò gómìnà Osun, wọ́n fojú balé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiiria, EFCC, ti fi ofin gbe awọn mẹta kan wa sile ejo giga niluu Osogbo lonii, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 ti a wa yii.
Ẹsun ti wọn fi kan awọn mẹta naa ni pe, wọn gba owo lọwọ ẹgbẹ oselu APC lati ta ibo wọn lasiko eto idibo sipo gomina nipinle Osun.
Orukọ awọn eeyan naa ni Adeyemo Bahiru Abiodun, Abidogun Ismail, Jimoh Kazeem ati Yekini Nurudeen Abioduna.
Lakoko ti wọn bere lọwọ wọn pe ṣe wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn tabi bẹẹ kọ, wọn ni awọn ko jẹbi ẹsun na rara.
Adajọ sọ fun agbẹjọro wọn pe ki wọn wa oniduro to jẹ oṣiṣẹ ijọba, ti ipo rẹ si ga de ipele kẹtala soke ati miliọnu meji naira
Lakoko ti BBC News Yoruba ba agbẹjọro wọn, N. T Adekilekun ati M. O Sambo sọrọ, wọn ni ko si otitọ kan pato ninu ẹjọ ti wọn fi kan awọn onibara awọn.
O tun tẹsiwaju pe kii ṣe APC nikan ra ibo, ẹgbẹ oṣelu PDP naa wa ninu wọn.
O sọ pe lotito ni pe wọn ti lo ọjọ merindinlogun ninu ahamọ EFCC niluu Ilorin ko to di pe awọn kọwe si EFCC lati gba itusilẹ wọn.
Nibayi, ile ẹjọ ti sun ẹjọ naa si ọjọ kọkanlelogun ati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii.














