Obìnrin tó lóyún nígbà 24 láàrin ọdún 23 tó sì pàdánù ọmọ 22 nínú wọn rèé

Oore ọtọọtọ ni Ẹlẹda a maa ṣe fun ọnikaluku laye ti wọn wa.
Bi awọn kan ṣe n rawọ ẹbẹ lati bimọ kan ṣoṣo arabinrin to wa ninu itan taa mu tọ yin wa yi kunlẹ ṣe abiyamọ ni igba mẹrinlelogun ṣugbọn meji pere lo ye ninu awọn ọmọ yi.
Imtiaz Fazil lorukọ rẹ o si bẹrẹ si ni loyun ni dun 1999.
Nigba ti yoo fi pe ọdun mẹtalelogun to bẹrẹ owo ọmọ bibi,oyun bajẹ mọ lara ni igba mẹtadinlogun ti marun un ninu awọn ọmọ yi ko si pe ọdun kan laye nitori ipenija ilera ti wọn ni.
Arabinrin ẹni ọdun mọkandinlaadọta yi ba BBC sọrọ to si ni o nira lati sọ nkan ti oju oun ri.
O ni niṣe loun pinu pe oun yoo sọ iriri oun nitori iru nkan bayi ṣoro sọ lagbegbe ibi to ti wa iyẹn ilẹ Aṣia.

Awọn mọlẹbi mii gaan kii sọrọ nipa iriri mi
Imtiaz Fazil sọ fun BBC ẹka to wa ni North West ilẹ Gẹẹsi pe niṣe lawọn mọlẹbi oun kii fẹ sọrọ nipa iriri yi nitori wọn maa n bẹru pe yoo mu ibanu wa toun ba sọ nipa rẹ.
''Ibanujẹ yi pọ nitori naa ni wọn kii fẹ mẹnu ba ọrọ mi''
''Wọn kan maa n de ọrọ naa mọra lai sọ fun ẹnikankan''
O ni pẹlu iri adanu ti oju oun ri, ko si ẹni to maa n beere pe bawo loun ṣe wa tabi ki wọn tiẹ ṣe aajo rẹ botile wu ko kere mọ.
''Ko si ọjọ kan to re kọja ti mi o ki n ṣe iranti awọn ọmọ mi''
Awọn nikan kọ lo n koju ipenija yi

Sarina Kaur Dosanjh ati ọkọ rẹ Vik ni iranti mimu opin ba ki obi maa dakẹ mọnu lori ọmọ ti wọn ba padanu .
Awọn mejeeji ti wọn jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn lati Walsall ni agbegbe West Midlannds ti ṣe idasilẹ ajọ ẹlẹyinju aanu kan Himmat Collective ti yoo maa faaye sisọ tọkan wọn silẹ fawọn tọkọtaya ilẹ Asia to ba padanu ọmọ wọn.
Tọkọtaya yi ti padanu ọmọ meji ti wọn ku ki wọn to bi wọn saye.
Wọn ni ẹdun ọkan yi jẹ nkan to ṣoro fawọn eeyan lati sọ nipa rẹ.
''Ọpọ lo maa n fọwọ rọ iṣẹlẹ yi danu ṣẹgbẹ''
Wọn fi kun ọpọ lo maa n yago fawọn ti ọmọ wọn ba ku lai to ibi ni paapa awọn ti wọn ba n gbiyanju lati loyun ki wọn si bimọ ti wọn naa.
''Wọn maa foju wo wa bi igba pe aisan to n ran eeyan ka si ẹlomiran ni nkan to ṣẹlẹ yi.''
Arabinrin Sarina ni ''Ọkan lara awọn idẹyẹsi taa gbọdọ ri pe a fopin si ree.''












