9/11 Baby: Aramanda ọmọ, wọ́n bi ní ọjọ́ 9/11, láago 9/11 tó si wọn 9/11

Oríṣun àwòrán, METHODIST HEALTHCARE
Ohun ayọ ati idunnu ni ti obi ba mojuba ọmọ tuntun ti wọn si ki kaabọ sile aye.
Amọ fawọn tọkọtaya kan nilẹ Amerika,idunnu ṣebi ẹni dara pọ mọ iyalẹnu nigba ti wọn bi ọmọ wọn lọjọ kẹsan (ayajọ 9/11) osu kọkanla, laago mẹsan kọja iṣẹju mọkanla.
Ko tan sibẹ, ọmọ naa tun wọn iwọn 9lb 11oz lori iwọn!
Nile iwosan Methodist LeBonheur Hospital ni Germantown, Tennessee ni wọn bi Christina Brown si.
Ọjọ ti wọn bi yi ṣe rẹgi pẹlu ayajọ ọdun kejila iklu 9/11 to waye lorileede Amerika.
Iṣẹ abẹ ni wọn gba fi bi Christina ti awọn olugbẹbi rẹ si n ṣe eemọ nigba ti wọn kede asiko ati ọjọ ti wọn bi.

Oríṣun àwòrán, METHODIST HEALTHCARE
Baba ikoko naa Justin Brown ni awọn ṣe emo nigba ti won kede asiko ti wn bi Christina ti o si ya awọn lẹnu pe ''wọn wọn ìwọn rẹ si bi ni 9/11, wọn bi ni 9/11 ni ọjọ 9/11''
''Ohun idunnu ni iru iroyin yi jẹ layajọ ọjọ ibanujẹ ''
Racheal Laughlin to jẹ olori awọn agbẹbi ni o ṣọwọn ki iru nnkan bayi ṣẹlẹ.
''Mo ti n gbebi ọmọ lati nnkan bi ọdun marundinlogoji ti mi o si ri ki ọjọ ibi asiko ati iwọn ọmọ papọ bayi ri''
Ayajọ ọjọ 9/11 lọjọ ti eeyan to le ni ẹgbẹrun mta padanu ẹmi wọn nigba ti awọn agbesunmọmi wa baalu kọlu ile nla World Trade Centre












