Ogunpa Fire: Ọjà olówó iyebíye jóná lọ́jà Ogunpa
Ariwo aje o, owo o, lo gba ọja Ogunpa nilu Ibadan kan lowurọ ọjọ Satide nigba ti apa kan isọ awọn to n ta ohun elo iranṣọ jona.
Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ, ko din ni ṣọọbu itaja bii mẹwa to fara kaasa iṣẹlẹ naa.
Iroyin o ṣe oju mi koro ti a gbọ jẹ ko di mimọ pe, o ṣeeṣe ko jẹ pe ọkan lara awọn ṣọọbu itaja naa ni ko pa ina ọba nigba ti wọn pari karakata tan lọjọ Ẹti.
- Àwọn ọmọ Ilara-mọkin yarí,wọn gbé'jà lọ bá Ọba láàfin
- Fídíò rèé tó ń sọ bí ọdún ìjẹṣu ṣe di ìjàgboro ní ìlú Ilaramọkin
- Ọkọ lu ìyàwó ọlọ́mọ mẹ́jọ pa tórí ó kọ̀ láti fún ọmọ l‘ọ́mú
- Ṣé YouTube ń jèrè nínú lílo ayédèrú fídíò ìwòsàn ààrùn jẹjẹrẹ?
- "Ọ̀pọ̀ àwàdà tí wọn fi ń ‘ṣun èmi àti Buhari lááyè’ lórí ayélujára ló jẹ́ iṣẹ́ ọpọlọ gidi"
Ina ọba to gbina ninu ọkan lara awọn sọọbu naa lo ran awọn yooku rẹ.
Gẹgẹ bi a tun ṣe gbọ, awọn ohun elo ẹṣọ aṣọ atawọn aṣọ olowo iyebiye lo jona ninu iṣẹlẹ ijamba ina naa.
Itaraṣaṣa awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ọyọ ti wọn pe, ni ko jẹ ki ọṣẹ ti ina naa ṣe pọ ju bi o ti mọ lọ.
Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko tii si ẹni to lee sọ ni pato ohun gan an to fa iṣẹlẹ naa.