'Ìdí tí a fi gbà láti wọ̣ àràmọ̀ndà fìlà kí a má ráyè ṣe màgòmágó lásìkò ìdánwò rèé'

Student 'anti-cheating' exam hats

Oríṣun àwòrán, MARY JOY MANDANE-ORTIZ

Aworan awọn akẹkọọ to wọ oniruru fila ti yoo mu ko ṣoro fun wọn lati ji iwe wo lasiko idanwo ti bẹrẹ si n fa ori ayelujra ya bayii ni Philipines.

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa, to wa niluu Legazpi lo ni ki wọn wọ awọn fila ti ko ni jẹ ki wọn maa ji iwe awọn akẹgbẹ wọn wo.

Eyii lo mu ki ọpọ ninu awọn akẹkọọ ọhun lo oniruru nnkan bii paali, atawọn nnkan mii lati ṣẹda awọn fila ọhun.

Student 'anti-cheating' exam hats

Oríṣun àwòrán, MARY JOY MANDANE-ORTIZ

Ọkan lara awọn olukọ naa sọ fun BBC pe o ti pẹ ti oun ti n wa ọna ti awọn akẹkọọ oun yoo fi ṣe olootọ lasiko idanwo.

Mary Joy Mandane-Ortiz, to jẹ Ọjọgbọn nipa eto ẹkọ imọ ẹrọ nile ẹkọ University College of Engineering, sọ pe aba naa ṣiṣẹ ju bi wọn ṣe lero lọ.

Mandane-Ortiz sọ pe erongba oun ni pe ki awọn akẹkọọ naan ṣe awọn fila kekere kan ti wọn yoo fi paali ṣe.

Iru nnkan bẹẹ ti waye ri

Lọdun 2013 ni aworan awọn akẹkọọ kan gbode ni Bangkok ti wọn wọf fila ti wọn I paali ṣe lati bo ẹgbẹ oju wọn lasiko idanwo ki wọn ma ba ji ẹlomiran wo.

O ni aworan ti ọdun 2013 yii lo fun awọn akẹkọọ oun ni iwuri lati ṣe oniruru aramọnda fila ti wọn ṣe lọdun 2022 yii.

Yatọ si awọn fila ti wọn fi pali ṣe, awọn miran wọ akoto alupupu, nigba ti awọn miran lo iboju Halloween.

MARY JOY MANDANE-ORTIZ

Oríṣun àwòrán, MARY JOY MANDANE-ORTIZ

Awọn akẹkọọ naa ṣe daadaa

MARY JOY MANDANE-ORTIZ

Oríṣun àwòrán, MARY JOY MANDANE-ORTIZ

Ọjọgbọn Mandane-Ortiz ni awọn akẹkọọ oun ṣe daadaa ninu idanwo naa nitori wọn kawe wọn daadaa lẹyin ti wọn ti mọ pe yoo ṣoro fun wọn lati ji iwe ẹlomiran wo.

O fi kun pe pupọ wọn lo tete pari idanwo naa, ẹnikẹni ko si ji iwe wo.