Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo gbé àbádòfin láti jà fún ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn tó ní ìpènijà ọpọlọ

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Abadofin naa to ni ifojusun lati maa daabo bo ẹtọ awọn eeyan to ni ipenija ọpọlọ n'ipinlẹ Ọyọ lo di gbigbe kalẹ lati ọwọ adari ile igbimọ aṣofin naa, Hon. Adebo Ogundoyin, igbakeji rẹ, Hon. Muhammad Fadeyi, adari ẹgbẹ oṣelu ti o pọ ju, Hon. Sanjo Adedoyin, adari ẹgbẹ oṣelu ti o kere ju, Hon Asimiyu Alarape ati Họnọrebu Saminu.
Lara awọn afojusun aba naa ni lati ṣe agbekalẹ awọn ibudo itọju fun awọn to ni ipenija ọpọlọ, ati awọn eka to n moju to iṣẹ ilu jakejado awọn ibudo eto ilera to n bẹ n'ipinlẹ Ọyọ, lati rii daju wi pe gbogbo ẹni to ni ipenija ọpọlọ lo ni ẹtọ si iru awọn ibudo eto ilera bẹẹ. Ti aba naa ba di ofin, yoo fi idi aabo to peye mulẹ fun awọn eeyan to ni ipenija ọpọlọ ati awọn ẹni ti aṣilo ogun oloro ti sọ di alaarẹ n'ipinlẹ ọhun.
Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ, adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Adebo Ogundoyin ṣe alaye wi pe abadofin naa lo duro gẹgẹ bii imuṣẹ ileri ti o ṣe ni ayajọ ọjọ ilera ọpọlọ l'agbaye fun ọdun 2022, eleyii ti o waye l'ọjọ kẹẹwa, oṣu kẹẹwa.
O ni, "Mo ṣe ileri nibi ayajọ ọjọ naa wi pe ipinlẹ Ọyọ yoo wa lara awọn ipinlẹ marun un akọkọ ti yoo sọ aba nipa ilera ọpọlọ di ofin lorilẹede yii.
A si ti wa lẹnu rẹ bayii gẹgẹ aba naa ṣe ti n jẹ kika fun igba akọkọ".
Ogundoyin tẹsiwaju wi pe igbesẹ lati sọ aba naa di ofin yoo ya kankan ki ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ le ni akọsilẹ aṣeyọri tuntun.
O ni ipinlẹ Ọyọ yoo tọ ipasẹ ipinlẹ Ekiti lati sọ aba naa di ofin laipẹ, gẹgẹ bi o ṣe n ṣalaye wi pe gbogbo iha aibikita ati oju ikorira ti awọn eeyan fi n wo ẹni to ni ipenija ọpọlọ n iyoo yipada lẹyin ti aba naa ba ti di ofin.











