Funke Akindele sọ̀kò ọ̀rọ̀ síjọba Eko lórí ‘àìkọbi ara rẹ̀’ sí ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀kún omi

PDP Eko ní ààbò ẹ̀mí àti dúkìá aráàlú ṣe kókó lásìkò àjálù ẹ̀kún omi ju ìpolongo ìbo lọ

Aworan Funke Akindele ati ẹkun omi

Oríṣun àwòrán, officialjandorandfunkejenifaakindele

Eto ipolongo ibo nipinlẹ Eko ti n gba ọna miran yọ pẹlu bi ẹgbẹ oselu alatako se lo ẹkun omi to waye nipinlẹ naa jọ lati polongo ibo tako ijọba to wa lori aleefa.

Ikọ olupolongo ibo fẹgbẹ oselu PDP, tii se alatako gboogi nipinlẹ Eko, ti wa n yọ suti ete di ijọba APC labẹ akoso gomina Babajide Sanwo-Olu lori ipo ti ipinlẹ naa wa.

Oludije fun ipo gomina fẹgbẹ PDP, Abdulazeez Olajide Adediran, ti inagijẹ rẹ n jẹ Jandor ati igbakeji rẹ, Funke Akindele si lo n kede bẹẹ.

Nigba to n salaye awọn ohun to mu ki wọn maa da siọ ijọba Sanwo-Olu naa loju opo Instagram rẹ, Funke Akindele ni aabo awọn olugbe ipinlẹ Eko lo n kọ awọn lominu.

Ajẹjade naa, ti ikọ ipolongo ibo fun Jandor ati Funke Akindele, ti wọn pe ni JA-FUN tabi JA FUN Eko fisita ni oun ti se ifikunluku pẹlu awọn eeyan to wa ni wọọdu kọọkan.

Ẹkun omi

Oríṣun àwòrán, officialjandorandfunkejenifaakindele

"Bi ijọba ipinlẹ Eko ko se tii kede pe nnkan ko fararọ lori isẹlẹ ẹkun omi buru jai"

Wọn ni ifikunlukun naa si lo fihan pe lootọ nijọba Eko fọnrere pe ẹkun omi yoo faye fawọn eeyan ipinlẹ naa amọ ko seto ilanilọyẹ tabi gbe igbesẹ lori bi aabo yoo se wa fun wọn.

“Bi ijọba ipinlẹ Eko ko se tii kede pe nnkan ko fararọ lori isẹlẹ ẹkun omi naa, paapaa lawọn agbegbe to wa ni ẹsẹ odo fihan pe ijọba n fi ẹmi awọn eeyan ta kátì ni.

Eyi si fihan pe ijọba Eko ko wulo, to si n fi ẹmi awọn araalu wewu, bẹẹ ni ọpọ awọn agbegbe to wa nipinlẹ naa si ni ko ni oju kọta tabi agbara to bode mu eyi ti yoo mu ki omi raye san lọ.

Koda, ọpọ awọn oju omi yii ni oju-oro ti kun ori wọn, ti wọn ko si raye san lọ, eyi to si n safihan pe ewu si n bẹ loko longẹ.”

Ikọ ipolongo ibo fawọn oludije mejeeji naa fikun pe oun yoo gba ijọba ipinlẹ Eko nimọran lati pasẹ fawọn ileesẹ rẹ to wa fọrọ ayika pe ki wọn wa ọna lati ko awọn idọti to n di oju agbara lọwọ.

Ẹkun omi

Oríṣun àwòrán, https://www.instagram.com/p/CkTXIwKtdkc/?hl=en

"O yẹ ki APC gbajumọ ipolongo ibo amọ araalu ko ni dibo ti ẹmi wọn ba wa ninu ewu"

Bakan naa lo ni ki ijọba APC tete wa ibugbe fun awọn eeyan ti ko nile lori mọ nitori isẹlẹ ẹkun omi yii.

“A tun n rọ ijọba Eko lati tete kede awọn nọmba ipe tawọn eeyan le maa pe si lasiko isẹlẹ pajawiri sita lawọn ileesẹ iroyin gbogbo.

O si tun yẹ ki wọn tete da awọn awọn eeyan ipinlẹ naa lẹkọ lori awọn igbesẹ to yẹ ki wọn gbe lasiko isẹlẹ pajawiri.

O si tun yẹ kijọba fi to araalu leti lati fi iroyin sọwọ si nipa awọn eeyan to ba ku lasiko ijamba pajawiri naa tabi awọn dukia to sofo”

Jandor ati Funke Akindele wa n gba ijọba APC nimọran pe lootọ lo yẹ ki wọn tẹnpẹlẹ mọ ipolongo ibo amọ awọn araalu ko ni kọbi ara seto idibo ti ẹmi wọn ba wa ninu ewu.

Awọn oludije mejeeji naa wa n rọ ijọba Sanwo-Olu ati ẹgbẹ oselu APC pe ko dide nilẹ lati da si ọrọ ẹkun omi naa, ko ba le dena ajalu nla to le fẹ waye lọjọ iwaju.