Èèyàn 151 kú, 82 míì ṣèṣe níbi ayẹyẹ àjọ̀dún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko di ni eeyan mọkanlelaadọjọ ti wọn ti tẹ pa nibi tawọn omilẹgbẹ eeyan ti korajọ nibi ayẹyẹ ajọdun Halloween ni Seoul, olu ilu South Korea.
Ko din ni eeyan mejilelọgọrin miran to farapa nibi ayẹyẹ naa to waye lagbegbe Itaewon nibi ti ayẹyẹ naa ti n waye.
Iroyin sọ pe n ṣe loku awọn eeyan ti wọn tẹ pa sun lori ara wọn nibi ayẹyẹ naa.
Ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ yii ko tii han si awọn alaṣẹ orilẹede naa.
Pupọ awọn to ku ninu iṣẹlẹ yii ni wọn jẹ ọdọ ti ọjọ ori wọn ko tii ju ogun si mọkandinlọgbọn lọ.
Ko din ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọrun to peju lati sami ajọdun Halloween
Mọkandinlogun ninu awọn to ku yii ni wọn wa lati ilẹ okeere.
Ko din ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọrun to peju sibi ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹ lati sami ayẹyẹ ajọdun Halloween fun igba akọkọ latigba ti ajakalẹ arun COVID-19 ti gbode kan.
Igba akọkọ niyi ti awọn eeyan yoo kora jọ fun ajọdun naa laisi gbedeke ijọba lori iye eeyan to yẹ ko pejọ pọ nitori ajakalẹ arun COVID .
Bakan ni igba akọkọ ree lẹyin ajakalẹ arun naa ti ijọba ko ni pọn ni dandan fawọn araalu lati lo ibomu lasiko ajọdun ọlọdọọdun naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi n fa awọn alaaye jade labẹ oku awọn ti wọn ti tẹ pa
Girigiri ẹsẹ to fa titẹ ara ẹni mọlẹ naa waye lopopona tooro kan, eyi to gba aarin ile kọja lagbegbe kan tori awọn ero to pọ ju iye to yẹ lọ, ti korajọpọ.
Awọn aworan ati fidio lori ayelujara fihan pe fọfọfọ ni ọna tooro naa kun, ti awọn eeyan ko si tilẹ ri aye rin daadaa.
Koda fidio kan fi han bi awọn eeyan ṣe n tiraka lati mi eemi sinu pẹlu.
Fidio kan tilẹ ṣe afihan bi awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣe n fa awọn eeyan jade labẹ oku awọn ti wọn ti tẹ pa to ga gegele.
Bẹẹ ni igbe ibosi ara adugbo n sọ kikankikan laarin awọn eeyan naa.
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ lorilẹede South Korea ṣi n ṣe iwadi lori ohun gan to fa wọlukọlu to ṣẹlẹ ti wọn fi n tẹ eeyan pa mọlẹ nibi ayẹyẹ naa.
Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni ori oke kan nibi ti awọn eeyan ti ṣubu laarin ọpọ ero nla eyi to mu ki awọn ero to n lọ tẹ wọn pa.
Olori ileeṣẹ panapana Yongsan Fire station, Choi Sung-beom ṣalaye fun ileeṣẹ akoroyinjọ Reuters pe iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bi agogo mẹwaa alẹ lọjọ Satide.
O ni awọn eeyan kan lo fẹsẹ kọ, ti wọn si n subu lori ara wọn ṣubu lasiko ayẹyẹ ọdun Halloween.
Iṣẹlẹ itẹnimọlẹpa to waye nilu Seoul yii ni eyi to tii buru julọ laarin ọdun mẹwaa sẹyin.
Laarin ọdun diẹ sẹyin, ọpọ ero ti pejọpọ lawọn ayẹyẹ kaakiri agbaye.
Iṣẹlẹ itẹnimọlẹpa to waye nilu Seoul lorilẹede South Korea yii wa lara awọn eyi ti ọpọ ẹmi ti sọnu julọ.
Eyi ni diẹ lara awọn isẹlẹ itẹraẹnipamọlẹ bii iru eyi to ti waye ri
Eyi ni diẹ lara awọn miran biirẹ to ti waye sẹyin:
Saudi Arabia: O le ni ẹgbẹrun meji eeyan ti iroyin sọ pe o ku nigba ti iṣẹlẹ itẹnimọlẹpa waye lasiko irinajo mimọ Mecca to waye lọdun 2015.
Indonesia: O le ni aadoje eeyan to padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ girigiri ẹsẹ ti wọn ti tẹ eeyan pa ni papa iṣire bọọlu kan ni Malang, East java nibẹrẹ oṣu kẹwaa ọdun 2022.

India: eeyan marundinlọgọfa lo ku – wọn tẹ awọn kan pa mọlẹ lasiko girgiri to waye, awọn miran si bomi l nigba ti wọn bẹ lati ori afara kan – nibi ayẹyẹ ọdun Hindu kan ni Madya Pradesh lọdun 2013.
Ivory Coast: ko din lọgọta eeyan to ku lasiko ayẹyẹ ọdun tuntun nigba ti awọn eeyan korajọpọ lati ṣayẹyẹ ọdun tuntun to wọle lọdun naa.
Aarẹ South Korea gbe iwadi kalẹ
Aarẹ orilẹede South Africa Yoon Suk-yeol ti pe ipade pajawiri kan to si tun ti gbe iwadii kalẹ lori iṣẹlẹ itẹnipamọlẹ to waye ni Seoul.
Igbimọ amuṣẹya kan pẹlu ti wa nikalẹ lati tọju awọn to fi ara ṣeṣe.
Olori ileeṣẹ panapana Yongsan Fire station, Choi Sung-beom ṣalaye pe “wọlukọlu to waye eyi to fa girigiri ẹsẹ ti awọn eeyan fi tẹ ara wọn pa” lo ṣokunfa iku ọwọọwọ naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe bi awọn eeyan kan ṣe n gbiyanju lati sa kuro laarin awọn ero naa ki wọn lee ri aye mi daradara ati bi awọn eeyan ṣe n ṣubu le ara wọn mọlẹ nibi ti ọgọọrọ ero, to wa ṣe ọdun Halloween, lo sokunfa ajalu naa.
Olori ileeṣẹ panapana Yongsan Fire station, Choi Sung-beom ṣalaye fawọn akọroyin “Awọn eeyan kan ṣubu lasiko ajọdun Halloween naa, ni oku fi di pupọ,”
Ọrọ ibanikẹdun latọdọ awọn aṣiwaju kaakiri agbaye
Ibanikẹdun ti n waye latọdọ awọn aṣiwaju orilẹede agbaye gbogbo.
Ọkan-o-jọkan awọn aṣiwaju orilẹede agbaye ni wọn ti n ranṣẹ ibanikẹdun si aarẹ orilẹede South Korea, ati awọn eeyan orilẹede naa.’
Olotu ijọba orilẹede Gẹẹsi, Rishi Sunak wa lara awọn aṣiwaju orilẹede agbaye to kọkọ ba South Korea atawọn eeyan rẹ kẹdun ajalu nla naa.
O ni “Iroyin laburu gidi leyi lati Seoul lalẹ yii.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bakan naa ni aarẹ orilẹede Amẹrika, Joe Biden pẹlu ti fi ọrọ idurotini ranṣẹ si South Korea lori ajalu naa.
Aarẹ Biden ati iyawo rẹ Jill sọ pe, “A n ṣọfọ pẹlu awọn eeyan orilẹede olominira Korea a si n fi ọrọ ikẹdun wa ranṣẹ pẹlu adura pe ki ọlọrun ṣe iwosan awọn to fara pa ni kankan.
“Ajọṣepọ laarin orilẹede wa mejeeji ṣi n gbopan si, bẹẹni okun ọmọ iya laarin awọn eeyan wa tun n gbopọn sii ni.
“Orilẹede Amẹrika duro ṣinṣin pẹlu South Korea ni asiko ikẹdun yii.”

Oríṣun àwòrán, US Whitehouse
Aarẹ orilẹede France, Macron ki awọn eeyan Seoul ati South Korea lapapọ ku ọrọ awọn ẹni wọn to lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Minisita fọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Antony Blinken pẹlu ti ba awọn eeyan Korea kẹdun lorukọ awọn eeyan orilẹede Amẹrika
“France yoo duro ti yin,” lasiko ipenija yii ni diẹ lara ọrọ ti Aarẹ Macron fi ranṣẹ loju opo Twitter rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Olotu ijọba orilẹede Canada Justin Trudeau naa fi ẹdun ọkan rẹ ranṣẹ to si ni “lorukọ awọn eeyan orilẹede Canada, oun ba awọn eeyan South Korea kẹdun ọfọ nla to ṣẹ naa.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4















