Gbogbo àṣìṣe Oyetola ni mà á ṣe àtúnṣe sí - Adeleke

- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Gomina ti wọn sẹsẹ dibo yan ni Ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti jẹjẹẹ pe oun ṣe atunṣe si gbogbo aṣiṣe ijọba Adegboyega Oyetola ni Ipinlẹ naa.
Adeleke sọ eleyi nigba ti o tẹwọ gba iwe esi iwadi awọn igbimọ to dasilẹ lori igbigba ijoba lọwọ Gomina Oyetola, O ni o dabi pe isejọba Oyetola mọmọ fẹ fi iya jẹ awọn eeyan nipinlẹ Osun ati awọn ohun alumọni.
O tẹsiwaju pe gbogbo ọna ni oun yoo gba lati ripe atunṣe de ba gbogbo ẹka ìjọba ìpinlẹ naa lasiko rẹ.
"Bii mo ṣe tẹwọ gba iwe yii loni, mo ma kaa daada lati ri pe mo ṣe ohun to tọ kete ti n ba ti de ijọba.
"Mo ri pe ẹ ṣe iwadi lori nnkan marun-un ti mo ṣe ileri fun awọn araalu. Lati igbayegbadun awọn osisẹ, idagbasoke, eto ẹkọ, eto Ilera, eto ọgbin, ẹka awọn obinrin, awọn ọdọ, eto abo, iyika ati idagbasoke ọrọ aje, gbogbo rẹ ni asẹtan lati mu wa si ìmuṣẹ.
"O ṣe ni lanu pe ẹni to ṣe ijọba, Gboyega Oyetola, ti mori le ọna ti ko da fun ipinlẹ Osun "Gbogbo awọn alumọni ipinlẹ Osun ni wọn ti ṣe akoba fun nitori ko le jẹ ti wọn nikan. "Mo wa ṣe ileri fun awọn araalu pe gbogbo awọn iwa yii ni ko ri ẹsẹ mulẹ ninu isejọba mii.
"Gbogbo awọn isẹ ti wọn gun le lẹyin ti wọn padanu ibo gomina ni ati bẹrẹ iwadi lori wọn.
"A yoo se atunṣe sì gbogbo ẹka ìjọba àti ipinlẹ Osun lapapọ."















