Ọlọ́pàá kan fi 'scissors' gún akẹgbẹ́ rẹ̀ pa ní téésàn

Oríṣun àwòrán, Other
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kebbi sọ pe oun ti bẹrẹ iwadii lori iku ọlọpaa kan, ASP Shu’aibu Sani Malumfashi, lẹyin to jà pẹlu akẹẹgbẹ rẹ kan.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Nafi’u Abubakar sọ fun BBC pe lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni ede aiyede waye laarin ASP Abdulaahi Garba ati ASP Shu’aibu Malumfashi, eyi to di ìjà.
Bi ija naa ṣe gbona ni ASP Garba mu sisọọsi (scissors) to si fi gun akẹẹgbẹ rẹ ni ẹ̀gbẹ́.
SP Abubakar sọ pe sisọọsi naa wọ inu ẹran ara rẹ, ti ẹjẹ si tu sita, to si ṣubu lulẹ.
“Ikorita naa ni DPO to wa ni agọ ọlọpaa ti gburo wọn, to si sare jade ni ọfiisi rẹ.
“Inu àgbàrá ẹ̀jẹ̀ si lo ba akẹẹgbẹ wọn, Malumfashi, ti wọn si sare gbe lọ sileewosan.”
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kebbi sọ pe iroyin naa ba awọn lojiji pe ija laarin ọlọpaa meji yọri si iku ẹnikan ninu wọn.
O ni nkan ibanujẹ ni pe ọlọpaa naa to fi ile rẹ silẹ ni owurọ pẹlu ilera pipe, amọ ti awọn wa mu iroyin iku rẹ lọ ba ẹbi rẹ nile pe akẹẹgbẹ rẹ pa a nitori ede aiyede.
SP Nafi’u Abubakar sọ pe awọn ti gbe ọrọ iṣẹlẹ naa lọ si olu ileeṣẹ awọn nilu Birnin Kebbi, fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ le ṣe iwadii lori rẹ lẹnu awọn ọlọpaa to wa ni agọ kan naa, ati idi ti gbogbo wọn fi salọ lasiko ija ọhun.
Afurasi naa, ASP Abdullahi Garba ti wa ni atimọle bayii titi ti iwadii yoo fi pari, ti wọn o si gbe e lọ sile ẹjọ.












