Ẹ jáwọ́ nínú ṣíṣe òṣèlú ẹ̀ta-inú - Seyi Makinde

Gboyega Oyetola àti Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti rọ àwọn olóṣèlú ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti jáwọ́ nínú ṣíṣe òṣèlú ẹ̀ta-inú àti èyí tó le dá omi àláfíà ìlú rú.

Makinde sọ èyí ní ìpínlẹ̀ Osun nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ kíkọ òpópónà Osogbo-Iwo-Ibadan-Iwo oní kìlómítà mọ́kànléláàdọ́rùn-ún.

Iṣẹ́ àkànṣe náà tó jẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti ìjọba Osun, Gboyega Oyetola ni wọn yóò ṣe fún oṣù méjìdínlógún.

Makinde nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Taiwo Adisa ní àwọn gómìnà méjéèjì le foríkorí láti fẹ́ ṣe ọ̀nà náà láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn àwọn le jẹ múkùndùn ìjọba àwaarawa bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kò sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà.

Ó ní ohun tí àwọn ń ṣe ní ìpínlẹ̀ Oyo ní láti ri pé gbogbo òṣèlú àwọn kò ní kọ́nú ń kọ́họ nínú àti pé ìṣèjọba kọjá ẹgbẹ́ òṣèlú lásán.

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ òṣèlú peoples Democratic Party (PDP) ni èmi ti wá, tí gómìnà ìpínlẹ̀ Osun sì wá láti All Progressives Congress (APC), síbẹ̀ àwa méjéèjì láti gbé ẹgbẹ́ òṣèlú wa tì láti ṣe iṣẹ́ tí àwọn ènìyàn wa yóò jẹ́ àǹfàní rẹ̀.”

Bákan náà ni gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola náà kan sárá sí akẹgbẹ́ rẹ̀ fún àjọṣepọ̀ láti ri pé ẹkùn ilẹ̀ Yorùbá rí ìdàgbàsókè.

Oyetola ní ó jẹ́ ohun tó dùn mọ́ òun wí pé Makinde gbà láti kópa nínú iṣẹ́ àkànṣe náà láì wò ó wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn yàtọ̀.