Èmi kọ́ ni mo pa ọ̀rẹ́bìnrin mi, gé ọrùn rẹ́ - Afurasí ọmọ ilẹ̀ China

Oríṣun àwòrán, others
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Ọmọ ilẹ China, Geng Quangrong ti sọ fun ileẹjọ giga ipinlẹ Kano pe oun ko jẹbi ẹsun ipaniyan lori iku arabinrin kan to jẹ ololufẹ rẹ, Ummukhulsum Sani Buhari, tí ọpọ mọ si Ummita.
Quangrong, ẹni ọdun mejidinlogọta ni wọn fi ẹsun kan pe o jawọ inu ile Ummita, ti o si gun un lọ bẹ ni agbegbe Jan-Bulo niluu Kano ninu oṣu kẹsan.
Nigba ti o sọrọ niwaju Adajọ Sanusi Ado Ma'aji ti ileẹjọ giga ipinlẹ Kano lọjọbọ ọsẹ yii, Quangrong ni oun ko jẹbi ẹsun ipaniyan naa rara.
O ni ẹsun tí wọn fi kan oun ni ko ni ẹsẹ nilẹ rárá.
Adajọ to dari Igbẹjọ naa, Adajọ Sanusi Ado Ma'aji ti wa sun Igbẹjọ sì ọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla lati fi tẹ awọn ẹri silẹ lori ẹsun naa
Óṣojúmikòró ṣàlàyé bí Geng Quangrong ṣé ṣékupa Ummita

Oríṣun àwòrán, others
Gẹgẹ bii awọn mọlẹbi ati awọn ara agbegbe naa ṣe ṣalaye fun ikọ BBC News, wọn ni ibaṣepọ kan wa laarin Ummukulthum Sani ati Geng ti idi ti iṣẹlẹ naa fi waye ṣe okunkun si awọn.
Osojumikoro ni wọn ti ge ọrun Ummu nigba ti awọn ri oku rẹ lasalẹ ọjọ Ẹti. Bappa Sani, ẹni to jẹ alabagbe ni Ummukulthum ti kọkọ ṣe igbeyawo tẹlẹ sugbọn ko pẹ ti wọn fi tuka ko to wa bẹrẹ ibasepo pẹlu ọmọ ilẹ China naa.
"A mọ ọ daadaa ni agbegbe wa, o ti ṣe igbeyawo tẹlẹ sugbọn ko pẹ ti wọn fi tuka, ko pẹ si igba naa ni a gbọ pe o fẹ ọmọ ilẹ China naa.
"Ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, emi ko si nile, awọn eeyan lo pe mi pe ọmọ ilẹ China naa fo igana wọle lati wọ ile gun Ummita lobẹ.
Ahmed Abdullahi, to jẹ ọrẹ si mọlẹbi náà ni awọn wa nile nigba ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ sugbọn awọn bọ sita lati lọ jẹun.
"Ile awọn Ummu ni mo maa n wa ni ọpọ igba nitori wọn jẹ bíi mọlẹbi mi, emi ati awọn ẹgbọn rẹ jada lati lọ jẹun ni ago mẹsan alẹ, kí a to de pada, a ti ba ọpọlọpọ eeyan niwaju ile wa.
"Ọrẹkunrin ni Geng jẹ si Ummu koda ko to ṣe igbeyawo ni wọn ti wa papọ. Gbogbo wa nile ni a mọ ọ koda a jọ maa n joko sọrọ niluu ile naa.
"Nnkan ti mo mọ ni pe wọn ni ede aiyede kan, ti Ummu si ni oun ko nifẹ si ibasepo wọn mọ, to si bi Geng ninu.
"Ileeṣẹ ọlọpaa mu Geng lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹsan ọdun 2022.















