Ẹ̀nikan fi ọ̀rọ̀ ọkọ bú mi àmọ́, Ọlọ́run ṣe oore tó já ayé láyà – Olorì Ooni Tobiloba

Oríṣun àwòrán, Tobi Philips
Ọkan lara awọn olori tuntun ni aafin Ile-Ife, Tobiloba Philips-Ogunwusi, ti sọrọ nipa bi eebu ori ayelujara ṣe di oore kanka to ya gbogbo aye lẹnu.
Ọsẹ meji sẹyin ni Ooni Adeyeye Ogunwusi fẹ Tobiloba gẹgẹ bi iyawo rẹ kẹta lẹyin ti Silekunola fi silẹ.
Olori Tobiloba to jẹ aranṣọ, sọ pe oun ti ṣeto riran awọn aṣọ igbeyawo fun tita ni fun ọpọlọpọ oṣu, amọ ti oun ko ri ẹni kankan lara awọn ọrẹ oun lati wọ wọn fi ya aworan fun ipolowo awọn aṣọ naa.
O ṣalaye pe nigba to ya, oun pinnu lati sẹ ipolowo naa funra oun.
“O pada ja si pe mo tẹ ẹlẹda mi lọrun pẹlu awọn aṣọ naa ti mo wọ, laimọ pe ma a ṣe igbeyawo laipẹ.”
Tobiloba sọ pe ni nkan bi oṣu Keje si oṣu Kẹjọ, ni ẹnikan sọ ọrọ ibanujẹ si oun lori ayelujara pe oun o le ri ọkọ fẹ, nitori pe afẹfẹyẹyẹ oun ti pọ ju.
“Ọrọ naa dun mi debi pe, o ba mi lọkan jẹ pupọ. Mo si sunkun tọ Ọlọrun lọ.
“Otitọ ibẹ ni pe mi o beere nkan pataki kankan lọwọ Ọlọrun lati bi ọdun kan.
“Ninu adura naa ni mo ti ṣe ileri fun Ọlọrun pe maa jẹri oore ni gbangba, nipa ijo ati orin ni gbogbo ọjọ Aiku ti yoo ba gbàá lati ṣe oore ti yoo já gbogbo awọn to ti ṣe ibi tabi sọ ọrọ eebu si mi, laya.”
Olori Tobiloba sọ pe Ọlọrun ṣe e nkan ti oun beere fun naa. Amọ o ni awọn to mọ itan aye oun nikan lo le ni oye ibi orisun itan aye oun.
Nkan to yẹ ki o mọ nipa Olori Tobiloba Philips-Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọmọ bíbí ìlú Erinje-Ikale ní Okitipupa ní ìpínlẹ̀ Ondo ni Tobi Phillips. Ile ẹkọ giga fasiti ilu Eko lo si ti kẹkọ gboye imọ ijinlẹ ninu imọ ninu ohun alumọni inu omi.
Òun ló ni iléeṣẹ́ gbajúgbajà aránsọ QTP Luxury Fashion tó sì ti ń ránṣọ ìgbàlódé láti ọdún 2018.
Yàtọ̀ sí aṣọ rírán Tobi jẹ́ arìnrìn oge láti ìgbà tó ti wà ní ilé ẹ̀kọ́.
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tí Tobi ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Blueprint lọ́dún 2014, ó ní ọdún 2009 ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rin ìrìn oge nígbà tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ilé ẹ̀kọ́.
Ó ní gbígbégbá orókè níbi ìdijé omidan Madam Tinubu Hall ní ọdún 2009 ló ṣí ojú òun sí ohun tí òun ti ń gbèrò láti ṣe láti kékeré òun wá.
Ìrìn oge ti gbé Tobi dé orílẹ̀ èdè South Korea nígbà tó lọ ṣojú àwọn ilé ẹ̀kọ́ ilẹ̀ adúláwọ̀ níbi tó ti gba oyè omidan ilé ẹ̀kọ́ gíga ilẹ̀ adúláwọ̀ àgbáyé (World Miss University Africa).
Ọjọ kẹsan an oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni Ọọni gbe e niyawo.














