Àwọn ọmọdé tó fipá bá ọmọbìnrin kan lòpọ̀, yá fídíò rẹ̀ kó sí gbaga ọlọ́pàá

Àwọn afurasí

Oríṣun àwòrán, Oyo Police

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti fòfin gbé àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ fẹ́sùn wí pé wọ́n fipá bá ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún lòpọ̀.

Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi síta ní yàtọ̀ sí wí pé wọ́n fi tipá bá ọmọbìnrin náà ló pọ̀, ní ṣe ni wọ́n tún yá fídíò ìbálòpọ̀ náà sórí fóònù wọn.

Lẹ́yìn tí wọ́n ya fídíò náà ni wọ́n tún fi ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ wọn mìíràn tí òun náà tún ń bèrè fún ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ ọmọbìnrin náà kí òun má fi fídíò ọ̀hún sórí ayélujára.

Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo, Adewale Osifeso fi síta ní lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹwàá ni ọmọbìnrin náà ṣe àbẹ̀wò sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọkùnrin kan, Joshua Adegoke, ọmọ ọdún méjìdínlógún ní ilé rẹ̀.

Nígbà tí ọmọbìnrin náà débẹ̀, ó bá ọ̀rẹ́ Joshua mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Peter Akintunde níbẹ̀.

Osifeso ní Joshua fi ẹlẹrìndòdò lọ ọmọbìnrin náà tó sì pè é sí yàrá lẹ́yìn náà fún ìbálòpọ̀ ṣùgbọ́n tí ọmọbìnrin náà yarí wí pé òun kò ṣe.

“Nígbà tó rí wí pé ó dàbí ẹni wí pé nǹkan mìíràn ti fẹ́ máa tẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà lọ ló bẹ Peter láti bá òun bẹ ọ̀rẹ́ kó jẹ́ kí òun máa lọ.”

“Àmọ́ dípò kí Peter bẹ ọ̀rẹ́ rẹ̀ níṣe ni òun náà sọ fún ọmọbìnrin náà láti gbà kí Joshua bá lòpọ̀.”

“Lẹ́yìn náà ni àwọn ọkùnrin méjéèjì fipá bá ọmọbìnrin náà lòpọ̀ tí wọ́n sì ya fídíò rẹ̀ sórí fóónù tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ wọn mìíràn.”

Osifeso fi kun pé gbogbo àwọn afurasí ọ̀hún ló ti jẹ́wọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀hún, tí wọ́n sì ń ran ìwádìí àwọn lọ́wọ́.

Yàtọ̀ sí àwọn afurasí yìí, Osifeso ní àwọn afurasí mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n mìíràn ni àwọn ti nawọ́ gan fún ìwà ọ̀daràn bí i ìjínigbé, olè jíjà àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn.

Bákan náà ló pàrọwà sáwọn òbí àti alágbàtọ́ láti mójútó àwọn ọmọ wọn láti tọ́ wọn sọ́nà lórí àwọn ìwà kò tọ́ àti àwọn ìwà mìíràn tó le da omi àláfíà ìlú rú.