Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí ìjọba àpapọ̀ san N500m fún Nnamdi Kanu, adarí IPOB

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ giga kan nilu Umuahia nipinlẹ Abia ti paṣẹ fun ìjọba àpapọ orilẹede Naijiria pe ko san ẹdẹgbẹta miliọnu Naira fun aṣiwaju ẹgbẹ ro n ja fun idasilẹ orilẹẹde ẹya igbo, Ipob, Nnamdi Kanu gẹgẹ bi owo gba maa binu, ki wọn si tun da ọrọ rẹ pada si bi o ṣe wa tẹlẹ.
L'Ọjọru ni ile ẹjọ gíga apapọ naa gbe idajọ yii kalẹ lori ẹjọ ti Kanu pe ìjọba apapọ niwaju ile ẹjọ naa.
Adajọ to gbọ ẹjọ naa, Onidajọ Evelyn Ayandike gbe idaju yii kalẹ lẹyin to bọ si aga igbẹjọ ohun lọjọ kẹrin oṣu kẹwaa. Loṣu kẹta ọdun 2022 lawọn agbẹjọro Kanu pe ẹjọ naa lati tako ohun ti wọn pe ni fifi agidi gbe Kanu kuro loke okun wa sile eyi ti wọn sọ pe o tako awọn ẹtọ rẹ gẹgẹ bi omoniyan.
Kanu n rọ ile ẹjọ naa pe ko ka ijọba apapọ lọwọ ko pe ko tun gbudọ gbe igbesẹ kankan mọ lati pe oun lẹjọ i2a ọdaran kankan pẹlu pe ko san ogun biliọnu naira owo itanran fun oun.
Agbẹjọro fun Kanu, Aloy Ejimakor ṣalaye ninu atẹjade rẹ pe bi ijọba apapọ ṣe fi tipa mu Kanu kuro lorileede Kenya tako ẹsẹ ìkẹrin abala ikejila iwe akọsilẹ ẹtọ omoniyan ti African Charter on Human and People’s Rights, pẹlu iwe ofin Naijiria
Amofin Ejimakor tun fi kun un pe ki ile ẹjọ ṣatunṣe awọn ọpọlọpọ itẹtọẹnimọlẹ to so rọ mọ igbesẹ naa bii ifiyajẹni, ifinipamọ si ahamọ lọna aitọ ati aifun un laaye lati gbọ tẹnu rẹ eyi ti ofin la kalẹ ki wọn to le gbe eeyan digbadigba kuro loke okun wa sile.
Bakan naa lo ni oun tun n rọ ile ẹjọ naa lati pase ki ijọba apapọ dẹkun pipe e lẹjọ ki wọn si fii silẹ si aaye to wa ṣaaju ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹfa ọdun 2021.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ni ọjọ kẹtala osu kẹwaa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja paṣẹ pe ẹsun ti ijọba apapọ fi kan Nnamdi Kanu ko l’ẹsẹ nlẹ.
Ileeẹjọ naa sọ pe bi wọn ṣe mu Kanu ati bi wọn ṣe fi tipa gbe e wa sorilẹede Naijiria ko ba ofin mu rara.
Amọṣa o, ijọba apapọ ṣi fẹ tako igbesẹ yii nile ẹjọ ro ga julọ lorilẹede Naijiria.















