Ọkùnrin tí kò wẹ̀ fún àádọ́ta ọdún kú ní ẹni ọdún 94

Amou Haji

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Amou Haji sọ pe laarin iho ilẹ kan ati yaara ti awọn aladugbo rẹ kọ fun ni oun n gbe

Ọkunrin kan ti kii ba ara adugbo ṣe, to da wa ni oun nikan ti wọn n pe ni ẹni to ya ọbun ju l’agbaye ti ku ni ẹni ọdun mẹrinlelaadọrun.

Iku rẹ waye lẹyin oṣu diẹ ti wọn wẹ fun lẹyin ọpọlọpọ ọdun.

O le ni aadọta ọdun ti Amou Haji ko fi fi ọsẹ tabi omi kan ara rẹ, nitori ibẹru pe o le mu ko ṣe aisan.

Ọpọ igba ni Haji, ọmọ orilẹ-ede Iran to n gbe nilu Fars ni Gusu orilẹ-ede ọhun, ti kọ igbiyanju awọn ara abule naa lati tun ara rẹ ṣe.

Ṣugbọn awọn ileeṣẹ iroyin ni arilẹ-ede naa sọ pe o gba lati wẹ loṣu diẹ sẹyin lẹyin ọpọlọpọ àrọwà.

Ileeṣẹ iroyin IRNA ni Iran sọ pe amọ ọkunrin naa dubulẹ aisan lẹyin ti wọn wẹ fun.

Aisan naa lo pada pa a lọjọ Aiku.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Tehran Times lọdun 2014, Arakunrin Haji sọ pe laarin iho kan to wa ninu ilẹ ati ile yaara kekere ti awọn aladugbo rẹ kọ fun ni abule Dejgah, ni oun n gbe.

O sọ fun akọroyin pe oun gbe igbesẹ lati sẹ bẹẹ nitori awọn iṣẹlẹ kan to ba oun lọkan jẹ nigba ti oun wa ni ọ̀dọ́.

IRNA sọ pe bi ko ṣe wẹ ti ko wẹ̀ fun ọpọlọpọ ọdun mu ki awọ ara rẹ kun fun eeri ati ètútú.

Wọn ni ẹran to ti bajẹ ati omi to dọti lo ma n mu.

Bakan naa lo tun fẹran lati ma a mu siga. Awọn awroran rẹ kan fihan bo ṣe n mu siga to ju ẹyọkan lọ lẹẹkan naa.

Ko si ẹni to mọ ẹbi Amou kankan, amọ awọn aladugbo rẹ n gbiyanju lati tọju rẹ

Oríṣun àwòrán, AFP

Gbogbo bi awọn ṣe ma n gbiyanju lati wẹ̀ fun si jẹ ibanujẹ fun.

Ṣugbọn ṣa, a ko tii le sọ pe lootọ ni oloogbe naa jẹ ẹni ti ko fi wẹ̀ fun igba to pẹ julọ ni agbaye.

Idi ni pe lọdun 2009, iroyin sọ pe ọkunrin kan ni India, ko tii wẹ̀ tabi fọ eyín rẹ fun ọdun marundinlogoji.

Ko si si ẹni to mọ nkan to ṣẹlẹ si lati igba naa.