Colombia fẹ̀yìn Flamingos Nàìjíríà gbolẹ̀ láti dé àṣekágba ìdíje FIFA u-17 Women's World Cup

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ agbabọọlu obinrin Naijiria ko ribi fi orukọ lelẹ ninu itan pẹlu bi wọn ko ṣe pegede lati kopa ninu aṣekagba idije FIFA u-17 Women's World Cup ni India.
Gbe silẹ gba sile ni wọn fi yanju ọrọ laarin awọn mejeeji lẹyin ti wọn gba ọmi ninu akoko ti wọn la kalẹ.
Goolu mẹfa si marun un ni Colombia ti fi ṣagba ikọ Flamingoes.
Pẹlu esi yi, wọn yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ fun ipo kẹta tabi ikẹrin idije naa.
Ni bayi, Colombia yoo koju ẹni ba bori laarin Germany ati Spain ninu aṣekagba idije yi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ifẹsẹwọnsẹ naa ko fi taratara gbona bi ọpọ ṣe reti.
Lọpọ igba lawọn ikọ Colombia ta felefele loju ile awọn ikọ Flamingoes ṣugbọn gbogbo igbiyanju wọn lati gba bọọlu si awọn ja si pabo.
Flamingoes naa gbiyanju ṣugbọn bi ọjọ ṣe n lọ ni wọn bẹrẹ si ni gbaradi de gbe silẹ gba sile ni ireti pe awọn yoo tun ri ọwọ mu bi ti igba ti wọn koju USA.
O ṣe bi ẹni pe adura yi ti gba nigba ti Colombia padanu ọkan ninu pẹnariti wọn ti aṣọle Flamingoes ribi mu.
Kurukẹrẹ wọn ba idije naa de ibi pe ki ọkan lara awọn Flamingoes gba pẹnariti rẹ ki gbogbo idije naa si pari.
Ibi ti ọrọ ti yi pada ree ti Edafe si kuna lati jẹ pẹnariti rẹ.
Colombia tẹsiwaju lati jẹ pẹnariti wọn to ku ṣugbọn kadara ti gbẹ wi pe Naijiria ko ni kọja abala idije yi.
Folorunsho lẹni to kuna lati jẹ pẹnariti to ja ireti ọpọ ọmọ Naijiria kulẹ patapata.

Oríṣun àwòrán, FIFA WOMEN'S WORLD CUP
Ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Naijiria ti ọjọ ori wọn koi to ọdun mẹtadinlogun yoo koju Colombia ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba, Semi Final idije 2022 FIFA u17 Women’s World Cup ni Ọjọru.
Aago mejila ọsan ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye, ni papa iṣere Pandit Jawaharla Nehru nilu Margao ni orilẹede India yoo ti waye.
Ọjọ Ẹti to kọja ni Flamingos ti Naijiria lu ikọ agbabọọlu America ni ami ayo mẹta si mẹrin.
Ọmi ayo kan ni wọn kọkọ ta, ko to di pe Naijiria bori pẹlu pẹnariti.
Ṣaaju ni ẹgbẹ agbabọọlu Flamingo fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ pẹlu Germany ni ipinB, ṣugbọn wọn pada ṣe daadaa nigba ti wọn na New Zealand ni ami ayo mẹrin si odo, ati Chile ni ami ayo meji si ẹyọkan.
Eyi to mu ki wọn o tayọ bọ si ipele Quater Final ti wọn ti lu agbabọọlu ilẹ America.
Ọdun 2012 ni awọn agbabọọlu u17 Naijiria ati Colombia kọkọ jọ koju ara wọn ni Azerbaijan, ti wọn ti na wọn ni ami ayo mẹta si odo.
Naijiria tun naa wọn ni igbakeji ti wọn pade ni Costa Rica lọdun 2014 pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan.
Amọ igba akọkọ niyii ti wọn jọ pade ni ipele Semi Final idije ife agbaye.
Bakan na lo jẹ igba akọkọ ti Flamingos yoo de ipele Semi Final ninu idije ife agbaye mẹfa ti wọn ti kopa.














