Man Utd bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ lórí fífí òpin sí iṣẹ́ Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti bẹrẹ awọn igbesẹ labẹ ofin, eyi ti yoo fun wọn ni anfani lati fi opin si iwe adehun wọn pẹlu atamatase ọmọ ilẹ Portugal, Cristiano Ronaldo.
O ti han gbangba pe Ronaldo ko ni le kopa mọ labẹ olukọni Erik ten Hag lẹyin to sọ awọn oko ọrọ kan ninu ifọrọwerọ kan to ṣe.
Ronaldo si ni oṣu mejọ to ku ni ninu iwe adehun rẹ to kọwọ bọ pẹlu ikọ Manchester United.
Manchester United ni anfani lati wogile iwe adehun pẹlu Ronaldo, eyi ti yoo fun ni anfani lati darapọ mọ ikọ agbabọọlu miiran to ba di ọdun to n bọ.
O ṣeeṣe ki Ronaldo ti gba ifẹsẹwọn to kẹyin fun Manchester United
Ifẹsẹwọnsẹ Manchester United pẹlu ikọ Aston Villa, nibi ti wọn ti fidi rẹmi ni ireti wa pe o le jẹ ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin fun Ronaldo pẹlu ikọ Manchester United.
Iroyin to tẹ wa lọwọ fi han pe awọn adari Manchester United ti bẹrẹ igbesẹ lori nkan ti wọn fẹ ṣe lori iwuwa si Ronaldo.
Awọn adari ni igbagbọ wa pe wọn fẹ yanju ọrọ Ronaldo ki abale keji ligi saa yii to bẹrẹ ninu oṣu kini ọdun to n bọ.
Kini Ronaldo sọ gan?
Ronaldo, ninu ifọrọwerọ kan to ṣe ni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United da oun, ti oun ko si ni apọnle kankan fun olukọni Ten Hag.
O ni wọn gbinyanju lati le oun kuro ninu ẹgbẹ agbabọọlu naa.
Ifọrewerọ ọhun lo gba odi lara awọn adari ikọ Manchester United, ti wọn si bu ẹnu atẹlu iwa ati igbesẹ Ronaldo lori ọrọ naa.
Ronaldo ni le waju ikọ agbabọọlu orilẹede Portugal lọ si orilẹede Qater nibi wọn yoo ti kopa ninu idije agbaye Fifa, eyi ti yoo bẹrẹ logunjọ oṣu yii.
Mọ̀ síi nípa ibi tí ọ̀rọ̀ Ronaldo dé dúró báyìí àti àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí yóò wáyé lálẹ́ òní

Oríṣun àwòrán, others
Atamatase agbawọwaju ikọ Manchester United, Cristiano Ronaldo ti darapọ mọ ikọ naa lẹyin ti akọnimọgba Erik Ten Hag palasẹ fun pe ko ma ṣe ìgbaradì fun ara rẹ.
Ronaldo, ẹni ọdun metadinlogoji ni o kọ lati kopa ninu ifẹsẹwonsẹ to waye lọsẹ to kọja pelu ikọ Tottenham, ti wọn si yoo kuro ninu awọn agbabọọlu to irin irinajo lọ koju ikọ Chelsea ni opin ọsẹ.
Ten Hag ni iwuwasi Ronaldo ni o ku diẹ kato, tí yoo si ri ijiya fun igbesẹ rẹ.
A rí gbọ pe ọpọlọpọ gbolohun lọ tí waye laarin Ronaldo ati Ten Hag laarin ọjọ diẹ sẹyìn.
Ronaldo ni orun to wa ni asiko naa lo fa ti oun fi kuro lori paapa lọ yara imura níbi ifẹsẹwonsẹ pẹlu ikọ Tottenham.
Ipadabọ Ronaldo ninu ikọ to n igbaradi lo sese ko fun ni anfani lati kopa ninu ifẹsẹwonsẹ iligi Uefa Europa níbi tí wọn yoo ti ma wa ko pẹlu ikọ agbabọọlu Sheriff Tiraspol lati orilẹede Moldova.
Bakan an ni Balogun ikọ agbabọọluq Manchester United, Harry Maguire ati Donny Van de Beek naa kopa ninu igbaradi naa lẹyin ti wọn farapa.
Wó àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí yóò wáyé lálẹ́ òní

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ agbabọọlu marun-un ni o ti peleke lọ ipele ẹlẹni mẹrindinlogun idije iligi Uefa Champion League sugbọn awọn wo ni yoo darapọ mọ wọn lalẹ oni
Ikọ Manchester City ti bori awọn akẹgbẹ wọn sugbọn ikọ Liverpool, Chelsea ati Tottenham sini isẹ lati ṣe.
Ikọ Liverpool nilo ami kan dondo lati pele sinu ipele ẹlẹni mẹrindinlogun ti wọn ba koju ikọ Ajax.
Ajax ni lati borí ifẹsẹwonsẹ pẹlu ikọ Liverpool, tí wọn si ni lati gba ju ami ayo kan wọle.
Tí Chelsea ba borí lalẹ oni, wọn yoo ni anfani lati kopa ninu ipele ẹlẹni mẹrindinlogun.
Wó àwọn ifẹsẹwonsẹ tí yóò wáyé lálẹ́ òní:
Salzburg v Chelsea
Dinamo Zagreb v Milan
Celtic v Shakhtar Donetsk
RB Leipzig v Real Madrid
Benfica v Juventus,
Paris St-Germain v Maccabi Haifa
Sevilla v Copenhagen
Borussia Dortmund v Manchester City

Oríṣun àwòrán, others















