Ọwọ tí tẹ mẹ́rin lára àwọn jàǹdùkú to ṣé ìkọlù sí ọkọ̀ ipolongo Adelabu ní ìpínlẹ̀ Oyo
Wọ̀n ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló rán àwọn - Comrade Femi Awogboro

Oríṣun àwòrán, others
Awọn igbinmọ to n ṣe agbatẹru ipolongo ibo fun oludije sipo gomina labẹ aisiya ẹgbẹ oṣelu Accord Party, Adebayo Adelabu ni agbegbe ijọba ibilẹ Atisbo ni ipinlẹ Oyo, ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa tẹ meji lara awọn afurasi ọhun kete ti wọn ṣe ikọlu naa.
Saaju ọsẹ yii, ni Oludije ọhun ke sita pe awọn ẹgbẹ oṣelu alatako yoku n gbero lati ṣe ikọlu si awọn oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord Party ni Ipinlẹ Oyo.
Nigba ti o ba ileeṣẹ BBC News Yoruba sọrọ, ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ Adelabu, Comrade Femi Awogboro, ni ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun bii awọn oloṣelu ati awọn akẹgbẹ to ni erongba lati di gomina ṣe nifẹ lati bẹrẹ ogun ni Ipinlẹ Oyo.

Oríṣun àwòrán, others
"Ni Satide tí a lọ ṣe ipade pẹlu awọn eeyan wa, tí tọmọde àti Ọba si tẹwọ gba wa pẹlu adura, bíi a ṣe setan pẹlu awọn eeyan ni bi ipade naa ni awọn janduku yìí jade ti wọn si lẹ okuta mọ ọkọ wa.''
"Ọwọ tẹ mẹrin lara awọn janduku ọhun tí wọn si jẹwọ fun wa pe ẹgbẹ oṣelu APC lo ran awọn.''
"Nigba ti a bí wọn pe kini ìdí tí wọn fi ṣe ikọlu, wọn ni nítorí pe ariwo ẹgbẹ oṣelu Accord lo gbalẹ, ti awọn ba si ṣe ikolu si wa, ariwo naa yoo walẹ."
Nibi ikọlu naa, meji lara ọkọ Adelabu ni wọn bajẹ àti ọkọ ipolongo ibo marun-un, pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ gbajugbaja oṣere tiata, Taiwo Soji, tí ọpọ mọ si 'Ose Ose Ọmọ Banke'.








