A kò ní fààyè gba ọtí títà àti rírà lásìkò ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé – Ijọba Qatar

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin to n jade lati Qatar ti fi han pe wọnm ko ni ta ọti lasiko idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye bẹrẹ lati opin ọsẹ yii.
Eyii ko ṣẹyin bi ajọ to n ri si ere bọọlu, FIFA, ṣe yi ipinnu rẹ pada lori ọrọ ọti ọhun.
FIFA ni wọn yoo si ta ọti lawọn agbegbe kan ninu papa iṣere lasiko idije naa, bo tilẹ jẹ pe ẹsin orilẹ-de naa ko faramọ ọti mimu.
Wọn ni awọn to joko ni aye awọn alẹnulọrọ nikan ni yoo le ra ọti lasiko idije Qatar 2022.
Ọjọ isinimi, ogunjọ oṣu Kọkanla, ọdun 2022 ti a wa yii ni idije ife ẹyẹ agbaye naa yoo bẹrẹ.
Budweiser, ọkan pataki lara wọn ileeṣẹ to n ṣagbatẹru idije naa jẹ ọkan lara ileeṣẹ AB InBev to n po ọti, o si ti gba aṣẹ lati ta ọti ni Qatar lasiko idije ife ẹyẹ naa.
Ninu atẹjade kan, FIFA sọ pe wọn ko ni ta ọti lagbegbe papa iṣere idaraya ti wọn yoo ti maa gba bọọlu.
O ni “Lẹyin ifọrọwerọ pẹlu orilẹ-ede ti idije naa yoo ti waye, a pinnu lati ta ọta lasiko ayẹyẹ awọn ololufẹ bọọlu nikan, atawọn agbegbe mii ti a ti gba aṣẹ.”
“A ko ni ta ọti lawọn papa iṣere ti awọn ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ti waye.
“FIFA ati orilẹ-ede ti idije naa yoo ti waye yoo ri daju pe awọn ololufẹ bọọlu gbadun ara wọn lasiko idije naa.”
“Igbesẹ yi ko ni nipa kankan lara bi wọn yoo ṣe ta ọti Bud Zero lawọn papa iṣẹre lasiko idije ife ẹyẹ naa.”












