Ìṣẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn òṣèlú 52 ló ti wáyé látìgbà tí ìpolongo ìbò ti bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà, Ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gẹgẹ bi ara igbesẹ lati dẹkun rogbodiyan lasiko idibo apapọ to n bọ lorilẹede Naijiria, oga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Baba Alkali ti ṣe ipade ida kọnkọ pẹlu awọn adari gbogbo ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to wa lorilẹede Naijiria.

Ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria kọminu lori awọn ikọlu to n waye sí awọn ileeṣẹ ajọ eleto idibo Naijiria, INEC lẹnu lọwọlọwọ yii kaakiri awọn ipinlẹ kan.

O tun ṣalaye lori ọna ati dẹkun awọn ikọlu yii at’awọn iwa ipa miran to n wọ tọ ignaradi fun eto idibo apapọ naa lẹyin bayii.

Oga ọlọọpa Baba Alkali ṣalaye fawọn akọroyin ṣaaju ipade ida kọnkọ naa pe o ṣe pataki lati fikuluku pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa nitori gbọnmọgbọnmọ iwa ipa ati rogbodiyan lagbo oṣelu ni Naijiria bayii.

“Ọna mẹta ni rogbodiyan oṣelu maa n gba ṣẹyọ. Akọkọ ni eyi to doju kọ awọn oṣiṣẹ ati dukia ajọ eleto idibo INEC gẹgẹ bi a ṣe n rii lọwọ ni ipinlẹ Ogun ati Osun.

“Ikeji ni laarin awọn ẹgbẹ oṣelu si ẹgbẹ oṣelu eyi to saba maa n pọ lasiko ipolongo ibo, idibo ati lẹyin idibo.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria naa ni ko din iṣẹlẹ rogbodiyan mejilelaadọta laarin ẹgbẹ oṣelu to ti tẹ ileeṣẹ ọlọọpa lọwọ kaakiri ipinlẹ mejilelogun lorilẹede Naijiria lati igba ti ajo INEC ti ṣi ilẹkun fun eto ipolongo idibo lati bẹrẹ lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun yii.

Lara awọn ẹgbẹ oṣelu to ran aṣoju sibi ipade naa ni African Action Congress (AAC), Peoples Democratic Party (PDP), All Progressives Congress (APC).

Bakan naa ni aṣoju ajọ INEC ati ileesẹ otẹlẹmuyẹ Naijiria, NIA, ileeṣẹ ologun at’awọn ileeṣẹ agbofinro miran pelu wa nibi ipade naa.