Ààrẹ Buhari kọ ìwé lọ gbélé rẹ fún olórí àjọ NYSC

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ja iwe lọ gbe ile rẹ fun Ọgagun Mohammed Fadah to jẹ adari ajọ Agunbanirọ, NYSC lorilẹede Naijiria.

Iroyin to fidi mulẹ ni aarẹ Buhari gbe igbeṣẹ naa ni Ọjọbọ, Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Kọkanla, ọdun 2022.

Fadah ni wọn yọ ni ipo lẹyin oṣu mẹfa to gba iṣẹ gẹgẹ bi adari ajọ NYSC ni oṣu karun un, ọdun 2022.

Iroyin ọhun ni wọn paṣẹ fun Fadah lati gbe iṣẹ silẹ fun ẹni to tẹle ni ipo ajọ naa.

Lasiko to gba ipo adari ajọ naa lo ṣeleri lati mu idagbasoke ba awọn agunbanirọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Aworan

Oríṣun àwòrán, NYSC

O tun fikun un pe eto igbayegbaju yoo wa fun awọn oṣiṣẹ ajọ naa.

Bakan naa lo pinu lati lo ero igbalode fun awọn agunbanirọ lati le ṣe iṣẹ wọn deede ni awọn igberiko ti wọn ba ti lọ sin ijọba.

Iroyin ọhun ni wọn paṣẹ fun Fadah lati gbe iṣẹ silẹ fun ẹni to tẹle ni ipo ajọ naa.

Ẹni ti wọn fi si ipo yoo wa nibẹ gẹgẹ bi fidiẹ titi ti wọn yoo fi yan ẹlomiran