Saliu Atagiroso: Kìí ṣe gbogbo eèyàn lò lè darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ àwa tí à ń pè sí orí rédíò

Àkọlé fídíò, Saliu Atagiroso: Kìí ṣe gbogbo eèyàn lò lè darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ àwa tí à ń pè sí orí rédíò

Sẹ lóòtọ́ ni pé àìníṣẹ́ lọ́wọ́ ló ń yọ àwọn tó máa ń pè sórí ètò rédíò lẹ́nu?

Oriṣiriṣi ẹgbẹ̀ tuntun ni awọn eeyan n da silẹ fun idagbasoke awujọ.

Egbe awọn to maa n pe lori eto sori afẹfẹ naa ti bẹrẹ ni Naijiria, eyi ti wọn pe ni Regular Callers On Radio Association.

Alhaji Saliu Atagisoro to jẹ alaga ẹgbẹ naa ṣalaye idi ti wọn ṣe da ẹgbẹ naa silẹ fun BBC.

O ni pe ki idagbasoke le ba awujọ ni wọn ṣe n pe sori eto nigba gbogbo.

Alhajiu Saliu Atagisoro salaye fun BBC nipa awọn ipa rere ti ẹgbẹ to n pe sori afẹfẹ yii ti ṣe lataari bi wọn ṣe n pe sori eto ti ijọba si n gbọ.

Bakan naa lo mẹnuba awọn amuyẹ ọmọ ẹgbẹ naa ni eyi ti ko nii ṣẹ pẹlu ẹgbẹ oṣelu kankan ni Naijiria.