Àdó olóró tí ìjọba fi ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ pa ọ́pọ́lọpọ̀ aráàlú ní Ethiopa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, John Alabi
- Role, Akọroyin BBC
Oṣoju mi koro kan ti sọ fun BBC pe ainiye awọn olugbe ilu Mandi lo sọ ẹmi wọn nu lati lẹyin ikolu lorilẹ-ede Ethiopia, eyii to jẹ kilomita ibusọ ẹẹdẹgbẹta, si olu ilu Addis Ababa.
Awọn olugbe Mandi ni iṣẹlẹ naa waye ni ọjo kanri lọjọru ọse yii ,lẹyin ti ikọ ọmọ ologun Oromo Liberation Army, OLA, to jagun gba ilu naa lọwọ ikọ ologun ijọba Ethiopia.
Olugbe ilu naa, ẹni to fi orukọ rẹ pamọ sọ fun akọroyin BBC pe ijọba lo ti n gbogun ti awọn ikọ agbegọn, sugbọn oṣeni laanu pe awọn ọmọ olugbe ilu lọ fara kasa iku ojiji.
Olugbe naa fi kun pe gbogbo ọkọ ayọkẹlẹ ati ẹyan to wa lagbe gbe ni ado oloro latoju ofurufu sọ wọn di ero ọrun.

Ọrẹ oṣojumi koro naa, to jẹ ajinhinrere, Tariku Wanna, to tun jẹ baba ọmọbinrin lenjelenje kan wa lara awọn to dero ọrun nigba ti wọn n jẹ ounjẹ ọsan.
Ẹlomiran to tun ba akọroyin wa sọrọ ni ko din ni ogun eeyan ti wọn ba iṣẹlẹ naa rin, ninu eyiti mejọ ninu wọn dero ọrun lẹsẹkẹsẹ, ti mẹtala yooku dero ọrun nileewosan nibi ti wọn ti n gba itoju latari pe wọn farapa yannayanna.
Bẹẹ, ileeseroyin BBC naa ko mọ onka awọn to farapa, bo tilẹjẹpe a gbiyanju lati waadi ni ileewosan ti wọn gbẹ wọn lọ.
Awọn oloṣelu ti bẹnu ate lu irufẹ ikọlu pẹlu awọn iko ọmọ ologun Oromo Liberation Army, OLA, eyii ti wọn ni ko bojumu, ti wọn si rọ ijọba lati dẹkun ninu sise iku pa awọn alaisẹ.
Ijọba Ethiopia ni ko ti sọrọ kankan lori iṣẹlẹ yii; BBC tun kan si ikọ ọmọ ogun Oromo, sugbon o kọ lati sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun bakan naa.












