Obìnrin kan bẹ́ sínú odò ọ̀sà lẹ́yìn tó bá oͅkoͅ àféͅsóͅnà rèͅ sòͅròͅ tán - LASEMA

Oríṣun àwòrán, lasema
Ileesͅeͅ to n risi oͅroͅ pajawiri nipinleͅ Eko, LRT ti kede pe igbiyanju sͅi n loͅ loͅwoͅ lati doola eͅmi obinrin ti woͅn sͅapejuwe pe, oͅdoͅbinrin to kosi inu agbami afara third mainland bridge, ni ilu Eko.
Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa waye.
Ninu ateͅjade ti agbeͅnusoͅ ajoͅ LRT, Olufemi Osantoyinbo fi lede ni igbiyanju sͅi n loͅ loͅwoͅ.
Ọgbẹni Osanyinbo ni awọn osͅisͅeͅ lati inu ajọ naa, awọn panapana, ati awọn ajọ mii lo kan lu omi lati sͅawari obinrin naa.
Bi isͅeͅleͅ naa sͅe sͅeͅleͅ?
Awoͅn ti isͅeͅleͅ naa sͅoju woͅn ni woͅn ri arabinrin naa ti ko ju eͅni oͅgboͅn oͅdun loͅ, to sọkalẹ lati inu oͅkoͅ takisi igbalode kan, lori afara Third mainland bridge,to si bẹ sinu omi.
Ajọ LRT sọ pe awakọ takisi to gbe arabinrin naa ni, "nisͅe ni arabinrin naa n fi ibinu soͅroͅ peͅlu oͅkoͅ afeͅsoͅna reͅ lori foonu, ki o to boͅ sileͅ ninu oͅkoͅ, to si loͅ kosi inu agbami.
A si n wa oͅdoͅbinrin to kosi inu omi- Lasema

Oríṣun àwòrán, lasema
Ajoͅ pajawiri nipinleͅ Eko ni awọn ko ri obinrin naa ninu omi titi di aago meje alẹ, ki awọn to pada sile nitori ilẹ ti ṣu.
Ajoͅ Lasema ni titi di asiko yii, awoͅn sͅi n wa obinrin naa, ti gbogbo osͅisͅeͅ LRT, Ileesͅeͅ panapana, ajoͅ eleto aabo DSS, wa ni ikaleͅ lati ri pe awoͅn doola eͅmi arabinrin naa.























