Ìyàwó mi àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti má n dáwọ́ lù mí ṣáàjú kí n tó dáná sun wọn - Joseph Ojo

Arakunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgọta, Joseph Ojo, ti wọn fi ẹsun kan pe o dana sun awọn ọmọ marun-un ti iyawo rẹ tuntun bi nilu Ondo, ti ṣalaye nkan to fa igbesẹ rẹ.
Ọgbẹni Ojo sọ fun BBC Yoruba ni olu ileeṣẹ ọlọpaa nilu Akure lọjọru pe asaasi ni oun le pe igbesẹ oun.
O ṣalaye pe oun ati Esther, to jẹ iyawo rẹ ati iya awọn ọmọ naa ti kọkọ ja ni alẹ ọjọ Ẹti to kọja, ti awọn ọmọ rẹ naa si dawọ jọ lu oun bi iṣe wọn.
“Ibinu naa ni mo fi lọ ra epo bẹtiro lalẹ ọjọ naa, ti mo si dana si yaara ti wọn sun si.
O ni ṣaaju ọjọ ti oun dana sun awọn ọmọ marun-un ti Esther Ojo bi fun ọkọ rẹ tẹlẹ ko to o fẹ Joseph, ni awọn ọmọ naa ati iya wọn ma n ba oun ja.
Ọgbẹni Joseph sọ pe iya wọn kii dana ounjẹ fun oun tabi ba oun fọ aṣọ.
O ṣalaye pe ti wọn ba se ounjẹ, wọn o ki n fun oun jẹ ninu rẹ botilẹ jẹ pe oun lo n pese owo ti wọn fi n jẹun.
“Iya wọn naa kii ba mi ṣe ohunkohun, epe lo tun ma n fi mi ṣẹ ti mo ba n jade pe mi o ni pada wọle.”
“Ti emi ati iyawo mi ba n ja, niṣe ni oun ati awọn ọmọ rẹ ma n pa ọwọ pọ̀ lu mi.”
Joseph ni gbogbo awọn nkan bẹẹ lo ma n ba oun ni ọkan jẹ
O ni awọn eeyan ti ba awọn da si tẹlẹ, amọ iyawo oun ko yipada.
Baba agba naa ni oun mọ pe ori bibẹ kọ ni oogun ori fifọ, amọ oun ko le ṣalaye nkan to mu ki oun dana sun awọn ọmọ naa
“Mo le sọ pe asasi ni igbesẹ mi nitori nkan ti mo sẹ ko bojumu.”
O ṣalaye pe oun ni awọn ọmọ mii yatọ si ọmọ meji ti Esther bi fun oun, oun si ni iyawo karun-un ti oun fẹ.
'Ibanujẹ ni iku ati irora awọn ọmọ mi jẹ fun mi'

Akinfolarin Liadi to jẹ baba awọn ọmọ marun-un naa sọ fun BBC pe ọsẹ to m bọ ni oun pinnu lati ko awọn ọmọ naa sọdọ ki ọkọ tuntun ti iyawo oun fẹ to dana sun wọn.
Ọgbẹni Liadi sọ pe iṣẹ oun ma n gbe oun kuro nile fun ọjọ pupọ, ni awọn ọmọ naa ṣe ma n duro lọdọ iya wọn.
"Ti mo ba ti pada de lati oko ti mo ti n wa katakata, wọn ma n wa si ile mi lati wa pẹlu mi."
Bakan naa ni Esther to jẹ iya wọn sọ pe oun bi ọmọ meji fun Ọgbẹni Joseph naa lẹyin ti oun fẹ ẹ.
Lọwọlọwọ, mẹta ninu awọn ọmọ marun-un naa ti ku.
Ẹnikan lara wọn lo kọkọ ku sinu ina naa, ọkan ku loju ọna ileewosan.
Ikẹta si ku ni Ọjọru lẹyin ọjọ kẹrin.












