Onímọ̀ nípa ètò ẹkọ sọ ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro tó n kojú ètò ẹ̀kọ́ ní

Àkọlé fídíò, Wàhálà ni dídá ọ̀pọ fásítì síll n fà

"Omi ti pọ ju ọka lọ ninu eto ẹkọ fasiti Naijiria"

Onimọ eto ẹkọ kan, Ọjọgbọn Abiola Odejide ti sọ pe aye igba ti ijọba le da gbe gbogbo bukaata eto ẹkọ fasiti ni Naijiria ti kọja.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba lo ti sọ pe bi awọn fasiti ṣe n fi ojoojumọ pọ si ti ba nkan jẹ.

O ni oun ranti gẹgẹ bi ọmọdebinrin, bi awọn kan sẹ gba baba oun ni imọran pe ko ma mu oun lọ sile ẹkọ nitori pe ile ọkọ ni oun yoo pari gbogbo irinajo si.

"Nigba naa, ile ẹkọ ko pọ rara, amọ baba mi pinnu lati ran mi lọ."

O ṣalaye pe oriṣiriṣi anfaani si ni ijọba n fun awọn akẹkọọ nigba naa.

"Nigba ti awọn fasiti to wa ni Naijiria ko pọ̀, ni ijọba ṣi le ma a gbe bukaata wọn. Amọ ni bayii ti wọn ti pọ, ti ijọba apapọ ati ipinlẹ n da silẹ bi ẹni pe wọn n fi iga gbaga, ko ṣeeṣe."

Ọjọgbọn Ayoade sọ pe eyi ko jẹ ki eto ẹkọ pojuowo bo ṣe yẹ mọ bi ti aye igba kan ti fasiti to wa kere.

O ni wahala ni dida fasiti silẹ lai mojuto awọn eyi to wa nilẹ tẹlẹ yoo ma a fa.

O fi igbesẹ naa we ti ẹni to bimọ tẹlẹ, to tun wa n bi si lai ni owo to fẹ fi tọju wọn.

"Laye atijọ, wọn kii fi oju kere awọn akẹkọọ to wa lati awọn fasiti bi ti ilu Ibadan, ti wọn ba lọ si oke okun. Idi ni pe wọn mọ pe "a ma n kawe to jọju".

Ayoade ni asiko ti to fun ijọba lati ronu bo ṣe le ma a ri owo. "Pẹlu bi nkan ṣe da bayii, eto ẹkọ ko le jẹ ọfẹ mọ, ti ijọba si gbọdọ le ṣe e pe awọn to ba lowo, ki wọn o sanwo.