Wo àwọn ohun mánigbàgbé mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Lam Adesina lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tó jáde láyé

Lam Adesina

Oríṣun àwòrán, premiumtimesng

    • Author, Adedayo Okedare
    • Role, Akọroyin BBC

Oni lo pe ọdun kẹwaa lẹyin ipapoda gbajugbaja oloṣelu to o tun jẹ Gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Oyo, Oloogbe Lamidi Onaolapo Adesina.

Ọdun 1939 ni wọn bi oloogbe naa to si jade laye lọdun 2012.

Wo awon nnkan mẹwa to jẹ manigbagbe nipa oloṣelu naa;

  • 'Lam Ade' gẹgẹ bi awọn ọrẹ ati ojulumọ rẹ ṣe maa n pee, ni a bi lọjọ Ẹti, ogunjọ, oṣu kini ọdun 1939, si idile Alhaji Olowoporoku Adio Adesina ati Arabinrin Ayisatu Asabi Adesina.
  • Lẹyin to pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ, o lọ si ile ẹkọ girama 'Loyola College, Ibadan,' ki o to lọ si ile eko giga fasiti orilẹede Naijiria to n bẹ ni Nsukka, laarin ọdun 1961 si 1965, nibi ti o ti kẹkọọ gboye akọkọ ni ẹka ti a ti n kọ nipa itan, 'History'. Lẹyin eyii ni o tun tẹsiwaju lẹnu ẹkọ ni fasiti ilẹ Ibadan lọdun 1971, nibi ti o ti kẹkọọ gboye ikeji.
  • Lẹyin ti o kẹkọọ pari ni fasiti lo bẹrẹ iṣẹ olukọ, ti o si ṣiṣẹ de ipo adari ile ẹkọ girama, 'Principal'. Ọpọlọpọ awọn idanilẹkọ to ṣe fun awọn akẹkọọ lo mu ojutu ba awon ipenija ti wọn n koju lẹnu ẹkọ wọn. Awọn akẹkọọ kan tilẹ fi idi rẹ mulẹ pe nipasẹ Oloogbe naa ni awọn ṣe ni anfani lati kọ idanwo aṣekagba ile ẹkọ girama, SSCE, lọfẹ.
  • Lam Adeṣina jẹ ọrẹ araalu, alatilẹyin ijọba awa-arawa ati adari ti o ni igboya, ti o si jẹ olotitọ.
  • Gẹgẹ bi Adeṣina ṣe jẹ gbajumọ ati ẹnikan ti araalu fẹran gidi gan lo mu ko jawe olubori lasiko ti o dije du ipo gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu 'Alliance for Democracy, AD, ninu eto idibo sipo gimina to waye l'ọdun 1999.
  • Wọn bura wọle fun Adeṣina gẹgẹ bii gomina tuntun l'ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun-un ọdun 1999, o si ṣe akoso laarin ọdun 1999 si 2003.
  • Lẹyin iṣejoba rẹ ni Oloye Rashidi Ladọja di gomina tuntun n'ipinlẹ Ọyọ ninu oṣu karun-un ọdun 2003.
  • Lam Adeṣina jade laye lọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun 2012, ni ile iwosan St. Nicholas Hospital to wa niluu Eko, o si wọ ka ilẹ sun ni ile rẹ to wa ni agbegbe Fẹlẹlẹ, ilu Ibadan, ni ilana ẹṣin Musulumi.
  • Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Oloogbe Abiọla Ajimọbi lo kede ipapoda Oloye Adeṣina nilu Ibadan. Lara awọn alaye ti Ajimọbi ṣe ni pe Adeṣina ni adari apapọ ẹgbẹ oṣelu Action Congress of Nigeria, ACN, titi di ọjọ ti o jade laye.
  • Nigba ti Oloye Lamidi Adeṣina ṣi wa l'aye, lara awọn nnkan ti o sọ pe oun fẹ ki awọn eeyan maa ranti nipa igbe aye oun ni awọn isẹ oloore ti o ṣe fun awọn eeyan rẹ, paapaa julọ nipa ajoṣepọ ti o ni pẹlu awọn ajafẹtọmọniyan bii Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati ja fun ijọba awa-arawa ati bi wọn ṣe gbe ina wo oju ijọba ologun ninu ẹgbẹ NADECO.