Ẹ̀yin gómìnà, ẹ fún wa láàyè láti kojú àwọn agbébọn lòpópónà Èkó sí Ìbàdàn

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Other

Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba , Iba Gani Abiodun Adams, ti kọminu lori bii awọn janduku ṣe n ṣe ikọlu si awọn arinrin ajo lopopona marosẹ Eko si Ibadan.

Aarẹ Gani Adams sapejuwe iwa awọn janduku naa gẹgẹ bii ohun itiju ati ẹdun ọkan fun ọun gẹgẹ bii ọkan lara agba ọjẹ nilẹ Yoruba,.

O ni awọn si ti kọ iwe si awọn gomina ni ipinlẹ Eko, Ogun ati Oyo lati fun awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ni anfani lati bawọn sisẹ pọ lati mu awọn odaran naa,

Nigba ti o ba ileeṣẹ BBC Yoruba sọrọ lori idi to fi fi iwe ransẹ si awọn gomina, Iba Adams ni lati ọdun to kọja ni awọn ti ri firifiri awọn ajinigbe ni awọn agbegbe kan lopopona morosẹ Ibadan si Eko.

''A si pe akiyesi ileeṣẹ ọlọpaa si i, pe ki wọn gba lati jẹ ki awọn a jọ sisẹ pọ sugbọn wọn kọ lati tẹlẹ imọran nigba naa.

“To ba jẹ pe nigba yẹn ni wọn ti gba pe ki a jọ sisẹ pọ, ko ni le to bayi sugbọn wọn kọ lati da wa lọhun, ti ọrọ si ti kọja eyi ti a le ma sọ."

ti wọn fi le ji igbakeji ọga agba fasiti ilẹ Ibadan.

Adams ni bi awọn ọlọpaa ko ṣe gbọ ti wa, la tun ṣe ni ki a ba awọn gomina ipinlẹ sọ ọ.

"A wa ti ni bii awọn agbofinro ba kọ lati da wa lohun, ṣebi a ni gomina, to jẹ olootu abo ni ipinlẹ, a si ti kọ iwe si gbogbo wọn nitori awọn araalu dibo yan wọn lati daabo bo ẹmi ati dukia wọn, ti wọn fun lasẹ lati jẹ olori."

O kesi awọn gomina ipinlẹ mẹtẹta lati fun ẹgbẹ Oodua Peoples' congress ni aaye, lati koju awọn ajinigbe ati agbebọn ni oju ọna naa.

Adams ni awọn ṣetan lati ṣiṣẹ yii pọ pẹlu awọn ileeṣẹ alaabo bi Amotekun ati awọn ọdẹ ibilẹ.

Ẹyin Gomina, ẹ pe awọn olori Amotẹkun ki a jọ sisẹ pọ

Iba Gani Adam wa kesi awọn Gomina lati fi aye silẹ fun ọmọ ẹgbẹ OPC lati sisẹ pọ pẹlu ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ogun, Eko ati Oyo lati da bobo ẹmi ati dukia awọn araalu ati awọn arin rinajo ti wọn lo opopona marosẹ Eko si Ibadan

Aarẹ ni awọn gbe igbẹsẹ lati dola ẹmi awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn n lo ọna naa lorekore, ti ọna ọhun si jẹ ọkan lara ọna ti lo si awọn ipinlẹ miiran lorilẹede Naijria.

“Aarẹ sẹtan lati ṣe nkan si ọrọ yii sugbọn asẹ wa lọdọ ijọba nitori a ko le kofiri lọ maa ṣe nitori awọn iriri wa pẹlu awọn agbofinro, wọn le yi ọrọ yii mọ wa lọwọ.

“Ọpọ igba ni ọrọ wa ti dibi mọ wa lọwọ, awọn ọmọ wa kan ti siṣe ti awọn ọlọpaa si sọ wọn di ọdaran, ki wọn ma wa ni pe Aarẹ ko ṣe nkankan si ọrọ yii, ni a fi sọ fun ijọba pe ki wọn wa ni aye

Gbogbo awọn agbebọn yii ni ọwọ awọn alaagbara kan ninu

Gani Adams salaye pe iwadii awọn ṣe ti safihan pe awọn alagbara kan lorilẹede Naijria n ṣe atilẹyin fun awọn agbebọn to n ṣe ikọlu lopopona marosẹ Eko si ibadan.

Aarẹ ni awọn alagbara yii pẹlu awọn mii nilẹ Yoruba ni agbara lori ọga agba fun ileesẹ ọlọpaa ati ọga agba fun ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijria , eyi to n fa ti awọn agbebọn ṣe ni igboya lati maa ṣe ikọlu si awọn arinrinajo.

“Ti eeyan ba fẹ ṣe isẹ abo bayi, o gbọdọ fi ọgbọn ṣe, ti eeyan si gbọdọ jẹ ki awọn eeyan mọ nipa rẹ, ki gbogbo aiye gtbọ si, ki eeyan to le sisẹ yẹn.

“Pẹlu ipo mi, n ko gbọdọ ṣe n kan lai fi to awọn ọmọ ilẹ Yoruba leti, nitori ipo gbogbo Yoruba ni mo dimu.

“Bi o ti lẹ jẹ awọn kan ko fẹ ilọsiuwaju ilẹ Yoruba , sugbọn a ma wo ọgbọn ti a ma fi ṣe, ki wọn ma pada wa ṣo di ibi mọ wa lọwọ.”