Wo ìdí tí Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ṣe kọlu ìpínlẹ̀ Abia

Aworan

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army

Ileeṣẹ ọmọ ologun lorilẹede Naijiria ti sọ idi ti wọn ṣe ikọlu si awọn agbegbe kan ipinlẹ Abia, eyi ti wọn ni ko ki n ṣe lati sẹruba awọn olugbe agbegbe naa, sugbọn lati dola ẹmi ọkan lara akẹgbẹ to wa ni ahamọ awọn ajinigbe.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ologun, Braigadier General Onyema Nwachukwu, to fi ransẹ si awọn akọroyin ni awọn balẹ si awọn agbegbe ọhun kete ti awọn gbọ iroyin pe ọkan lara awọn, Bassey Ikunuwan, wa ni ahamọ awọn ajinigbe.

Ileeṣe ọmọ ologun ni awọn ti ṣekupa awọn afurasi ajinigbe meji, ti awọn si ṣe alabapade awọn ohun ija lọwọ wọn pẹlu.

Iwadii lori ijinigbe ọkan lara wa lo waye

Aworan

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army

Lọjọbọ ọsẹ yii, awọn ọmọ awon ajijangbara Indigenous People of Biafra (IPOB) fẹsun kan ileeṣẹ ọmọ ologun pe wọn ṣe ikọlu si awọn olugbe agbegbe Amangu, to si tun ni wọn gbẹmii awọn eeyan kan.

“Ẹsun ti wọn fi kan wa le pupọ, ẹtọ wa si ni gẹgẹ bii ileeṣẹ ọmọ ologun lati sọ idi otitọ ọrọ ọhun, eyi to yatọ si ohun ti wọn a ṣe.”

Agbẹnusọ Nwachukwu ni Bassy Ikunugwan lo gba isimi lẹnu isẹ lati lọ sile, to si bọ si ọwọ awọn ajinigbe lopopona Okwu-Ebem Ohafia nipinlẹ Abia lọjọ keji oṣu kọkanla.

“Lọjọ kẹta, awọn ọmọ bẹrẹ iwadii lẹyin ti a ri gbọ pe awọn pe ọmọ IPOB ati ESN gbe Basssy lọ sini abulẹ Amangu.

“Nigba ti a ṣe awari wọn, ija bẹ silẹ ti wọn si sina bọlẹ fun wa. Lọjọ kẹrin a tẹsiwaju lori irinajo wa lati ṣe awari akẹgbẹ wa, a si morile Okon Aku nipinlẹ Abia, ọwọ tẹ ọkan lara awọn ajinigbe ọhun pẹlu Ibọn Ak47, ọta ibọn ati ẹrọ ibanisọrọ.”

Lọjọ karun un, a morilẹ abule Amangu, nibi ti awọn ajinigbe ọhun saa si, a mu meji balẹ ti awọn yooku si salọ.

Nwachukwu wa rọ awọn olugbe abule Amangu lati ma ṣe foya rara nitori pe bi ilu yoo ṣe da ati bi awọn yoo ṣe dabo bo ẹmi ati dukia wọn ni awọn gbajumọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army