Iléeṣẹ́ tó ni Facebook, Meta, ṣàlàyé èrèdí tó ṣe fẹ́ d́a 11,000 òṣìṣẹ́ dúró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Meta, ileeṣẹ to ni Facebook, WhatApp ati Instagram ti ṣalaye eredi to ṣe fẹ gba iṣẹ lọwọ ida mẹtala awọn oṣiṣẹ rẹ kaakiri agbaye.
Idaduro ọlọgọrọ ero yii ni akọkọ iru rẹ nileeṣẹ naa, to n tumọ si pe ẹgbẹrun mọkanla ninu ẹgbẹrun mẹ́tàdínláàdọ́rùn ún awọn oṣiṣẹ naa kaakiri agbaye ni yoo padanu iṣẹ wọn.
Ọga agba ileeṣẹ ọhun, Mark Zuckerberg ni idaduro naa lo nira ju fun oun gẹgẹ adari ileeṣẹ Meta lati igba ti oun ti da a silẹ.
Iroyin idaduro yii lo n waye lẹyin ti ileeṣẹ Twitter ti kọkọ jawe ẹ lọ gbele yi fun idaji awọn oṣiṣẹ rẹ.
Zuckerberg sọ ninu atẹjade kan pe “Mo mọ pe ko rọrun fun gbogbo wa, mo si ba gbogbo awọn ti ọrọ naa kan kẹdun.”
O ni eredi igbeṣe lati da awọn eeyan naa duro ko ṣẹyin ireti awọn pe ileeṣẹ naa yoo jere gọbọi lasiko ajakalẹ arun Corona, amọ ọrọ naa bẹyin yọ.
Igbesẹ to kan fun Meta
Zuckerberg ti sọ pe ileeṣẹ oun yoo dojukọ awọn ohun tuntun ti yo pa owo wọle fun ileeṣẹ naa bayii, bii imọ ẹrọ Artificial Inteligence, AI, ipolowo ọja ati Metaverse.
Meta yoo tun di iye owo to n na ku lawọn ẹka kan bii owo to n na lori ile kikọ, ọọfisi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn oṣiṣẹ ti idaduro yii kan yoo gba iwe idaduro wọn laipẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn lanfani lati bere awọn ibere to rọ mọ ọjọ iwaju wọn.
Ẹwẹ, awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun nilẹ Amẹrika atawọn orilẹ-ede mii ti ọrọ naa kan yoo gba awọn ẹtọ to tọ si wọn labẹ ofin.












