Àwọn olùkọ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ Fásitì UK yóò gùnlé ìyanṣẹ́lódì nínú oṣù yìí, èrèdí rèé

UCU

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn olukọ fasiti atawọn oṣiṣẹ fasiti mii nilẹ Gẹẹsi ti sọ pe awọn yoo da iṣẹ silẹ ninu oṣu Kọakanla, ọdun 2022 yii.

Eredi iyanṣẹlodi wọn naa ni wọn sọ pe ko ṣẹyin owo oṣu, owo ifẹyinti atawọn idojukọ mii ti wọn n ri lẹnu iṣẹ.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti naa, University and College Union, UCU, sọ pe iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta naa yoo waye lọjọ kẹrinlelogun, ọjọ karundinlọgbọn ati ọgbọ ọjọ oṣu Kọkanla yii kaakiri aadọjọ fasisiti ni UK.

UCU ni yoo le ni ẹgbẹrun lọna aadọrin oṣiṣẹ ti yoo maa wo iṣẹ loju fun gbogbo ọjọ mẹta naa.

Ninu atẹjade to fi lede, wọn ni awọn akẹkọọ naa faramọ iyaṣẹlodi ọhun, eyii ti yoo ṣe ipalara fun ẹkọ miliọnu meji abọ ninu wọn.

Ẹgbẹ ọhun ni “A ṣetan lati daabo bo ẹtọ awọn akẹkọọ, lootọ ni iyanṣelodi naa yoo ṣe ipalara fun miliọnu meji abọ ninu wọn amọ o ṣeeṣe ko ma maye ti awọn to gba wa siṣẹ ba tete gbe igbesẹ lati yanju awọn ohun ti a n bere fun.”

Eredi iyanṣẹlodi naa

UK University staff protest

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ara idi ti awọn ṣolukọ naa ṣe n gunle iyanṣẹlodi ni owo ifẹyinti wọn, ọrọ naa si ti wa nilẹ kii ṣe ọrọ ọdun mẹwaa.

Ọrọ naa tun gbori jade lẹẹkan si lẹyin ti awọn oṣiṣẹ fasiti naa bẹrẹ si n lo eto Universities Superannuation Scheme, USS, fun owo ifẹyinti wọn, eyii ti wọn ni ko muna doko.

Idi miran ti wọn tun fi n yan iṣẹ lodi ni owo oṣu wọn.

Ṣaaju ni awọn alaṣẹ ti kọkọ n gbero afikun owo ọsu awọn olukọ naa pẹlu ida mẹta, nigba ti awọn oṣiṣẹ ti ipo wọn kere yoo ni afikun owo oṣu pẹlu ida mẹsan an, amọ UCU yari kanlẹ pe owo naa ti kere ju.

Ki ni ijọba UK sọ nipa iyanṣẹlodi yii?

UK student Union

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minisita eto ẹkọ, Robert Halfon sọ pe iyanṣẹlodi naa ko dun mọ oun ninu, o si ti parọwa si gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lati fori kori lori ọna abayọ.

O ni ki akẹkọọ to ba gbagbọ pe iyanṣẹlodi naa yoo pa oun lara pe UCU lẹjọ.

Halfon sọ pe o yẹ ki UCU wo bi eto ọrọ aje ṣe ri lagbaye, paapaa lasiko yii ko to ma ronu nipa iyanṣẹlodi.

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn akẹkọọ ti sọ pe digbi lawọn wa lẹyin awọn oṣiṣẹ fasiti fọhun un iyanṣelodi naa ti wọn n mura rẹ.