Orílẹ̀èdè Kenya àti South Africa ti kéde ìgbésẹ̀ físà ọ̀fẹ́ láàrin ara wọ́n

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Kenya ati South Africa ti gba lati mu igbesẹ 'Free Visa' fun awọn ọmọ orilẹede Kenya to ba fẹ lọ si orilẹede South Africa fun aadọrun ọjọ lati ninu oṣu kini ọdun to n bọ

Tẹlẹ awọn ọmọ Kenya to fẹ wa si South Africa nilo lati san owo to to ogoji dọla fun aadọrun ọjọ pẹlu awọn ohun ifowopamọ miiran.

Awọn ọmọ orilẹede South Africa, ni anfani si 'Free Visa' yatọ si awọn ọmọ orilẹede Kenya tẹlẹ

Orilẹede mejeeji kede igbesẹ ọhun lẹyin ti ijiroro to waye larin Aarẹ William Ruto ti Kenya ati Cyril Ramaphosa ti South Africa nile ijọba ni Nairobi lorilẹede Kenya.

“Mo fẹ fi ẹmi imoore han lori igbesẹ ti a gbe loni lori fisa ọfẹ laarin orilẹede Kenya ati South Africa,” Aarẹ Ruto salaye

Bakan naa ni awọn olori naa fi ẹnu ko lati yi ipinnu wọn pada ti irufin ba waye larin wọn.

Fun ọpọlọpọ ọdun ni ija n lọ laarin awọn mejeeji iori ọrọ fisa ọhun.

Ifi ẹnuko lori ibaṣepọ ileeṣẹ ọkọ ofurufu

Ẹwẹ, awọn olori naa ti pinnu lati tẹsiwaju lori ibaṣepọ ileeṣẹ ofurufu laarin Kenya Airways ati South Africa Airways, eyi ti wọn ti wọn buwọlu lọdun 2021.

Aarẹ Ramaphosa ni, “Ajọ ni erongba kana,ti a si nilo lati jọ sisẹ papọ lati mu wa si imusẹ.”

Wọn ko ti kede bii ibaṣepọ ọhun yoo ṣe waye, to si jẹ pe awọn ileeṣẹ mejeeji duro le awọn ijọba fun owo ati awọn nkan miiran.

Iyana ọrọ eto aje to mẹyẹ

Orilẹede mejeeji tu bọwọlu iwe adehun fun ajọṣepọ lori awọn ẹka ijọba lati mu ilọsiwaju wa.

Lọdun 2021, Kenya gbe ọja toto milọnu mẹtalelọgbọn dọla lọ South Africa, eyi to jina si mẹjọlenirinwo milọnu owo dọla ti Kenya fi ra ọja lati South Africa lọdun naa.