Lítà bẹntiró yóò di N410 láì sí owó ìrànwọ́ orí epo 'Sọ́búsídi' - NNPC

aworan

Oríṣun àwòrán, MELEKYARI/FACEBOOK

Ọga agba fun ajọ NNPC orilẹede Naijiria, Mele Kyari, sọ pe iye owo lita epo bẹntiro kan yoo di N410 fun tita, dipo N170, eyi ti wọn ta lọwọlọwọ, ni kete ti ijọba ba yọ ọwọ iranwọ ori epo kuro.

O sọ eleyi nibi apero kan to waye niluu Abuja pẹlu awọn aṣofin lorilẹede Naijiria. O ni o nira diẹ lati maa ta epo bẹntiro ni N170 nitori o ju iye rẹ lọ.

“Ẹnikan ni lati fi ara gba n to sẹlẹ yii, sugbọn ohun to lọ lọwọ yii ni ko ni pẹ rara.”

IPMAN, sọ pe awọn fẹ ki ijọba fi owo le owo epo latiri bi awọn ṣe dojukọ ọplọpọ lasigbo ni igba ti wọn ba n gbe epo wọle.

Ẹgbẹ ọhun ni igbesẹ ọhun ni yoo ni yoo mu dikun ba bii epo bẹntiro ṣe n safẹrẹ lorilẹede Naijira.

Wọn ni pe yiyọ owo iranwo ori epo kuro ati ki afikun de ba owo epo nikan ni ojutu si iṣoro ọwọn gogo epo bentiro lorilẹede Naijiria.

Sugbọn nigba to n sọrọ niwaju awọn ọmọ ile igbimọ asofin agba, alaga NNPC sọ pe ohun faramọ ifowokun owo epo bentiro lasiko yii nitori o soro lati tesiwaju lati maa ta epo pentiro ni 170 naira.

Mele Kyari nii lati ibẹrẹ ọdun yii titi di akoko yii, ko ti si igba kankan ti iṣoro ọwọn gogo epo ko sẹlẹ, ti o si faa ayipada owo lita epo bentiro ti di akọkọ yii.

Wó ìdí tí IPMAN ṣe fẹ́ fí owó kún owó epo bẹntírò ní Nàìjíríà

aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ awọn alagbata epo rọbi, IPMAN ti pe fun pe ki wọn gbe owo le epo bẹntiro.

Nitori ọna ti wọn n gba gbe epo wọ ilẹ yii nira pupọ, ti igbesẹ naa si ti fi opin si bi epo bẹntiro se n safẹrẹ lorilẹede Naijiria.

IPMAN se alaye yii lati koju bii awọn agbegbe kan ni Naijiria ṣe ti n koju airi epo ra paapa julọ ni apa Ariwa ati olu ilu Abuja.

Nigba ti o n ba ileeṣẹ BBC News sọrọ, olori ẹgbẹ ọhun ni apa ariwa orilẹede Naijiria, Bashir Dan Mallam ni awọn ni lati bọ sita sọ otitọ fun awọn ọmọ Naijiria nitori nkan ti awọn la kọja lati gbe epo wọ ilẹ nira lọpọlọpọ.

O ni awọn apa ibi kan lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ lati ma taa epo bẹntiro ni aadọwaa naira.

Bashir ni iye ti ijọba ni ki awọn maa ta epo bẹntiro ni mọkandinlaadọsan naira sugbọn bii nnkan ṣe ri ati wahala ti awọn ṣe ki awọn to gbe de ile epo, awọn yoo ma taa epo naa ni mẹrinlelaadọwaa naira.

“Ti a ko ba ta bayen, a ti padanu ni ọpọlọpọ.

“Ko ni n ṣe pe ko si epo bẹnitiro sugbọn ọna ti a gba lati gbewọ orilẹede Naijiria lo nira gan fun wa.”