Wo àwọn àgbábọ́ọ̀lù tí kò ní kópa nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù àgbáyé nítorí wọn farapa

Oríṣun àwòrán, others
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Idije ife ẹyẹ agbaye jẹ idije kan ti ọpọ awọn agbabọọlu maa ni erongba lati kopa ninu rẹ sugbọn nigba mii, ọpọ wọn ni ko ni anfani lati kopa nitori wọn ti farapa.
Saaju idije ife ẹyẹ agbaye, eyi ti yoo bẹrẹ ninu oṣu kọkanla lorilẹede Qatar, ọpọ awọn gbajugbaja agbabọọlu ni ko ni kopa ninu eyi ti wọn ti wọn sapejuwe pe o dun awọn pupọ sugbọn ilera awọn ṣe koko.
BBC News Yoruba ti wa ṣe akojọ awọn agbabọọlu ti ko ni anfani lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye lorilẹede Qatar.
Paul Pogba
Pogba ko ti ni anfani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan lati igba ti saa tuntun ti bẹrẹ lẹyin ti o fi orunkun sẹṣe.
Igbagbọ nipe yoo pada lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye sugbọn kete to pada de ni o tun lugbadi ikọlu miiran, eyi ti ajọ ere bọọlu lorilẹede France fi wa kede pe Pogba ko ni le kopa ninu idije.

Oríṣun àwòrán, others
N’golo Kante
Ẹlomiiran ti awọn ololufẹ tun banujẹ pe ko ni kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye ni N’golo Kante.
Agba ọwọ aarin fun ikọ Chelsea ati France lo kopa ribiribi lati ri pe orilẹede France gba ife ẹyẹ agbaye lọdun 2018 ati bi ikọ Chelsea ṣe gba idije Uefa Champions League lọdun 2021.
Igba ikẹyin ti Kante kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye laarin ikọ Chelsea ati Tothemham, nibẹ lo fi farapa, ti wọn kede pe yoo lo oṣu diẹ ko to pada lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Reece James
Ọmọ orilẹede England, Reece James, ko ni anfani lati mu erongba rẹ wa si imusi lẹyin to fi orunkun rẹ ṣeṣe ninu ifẹsẹwọnsẹ ikọ Chelsea ati ikọ Ac milan.
Iwadii awọn onimọ iṣegun ni James nilo oṣu meji lati fi ṣe itọju ara rẹ

Oríṣun àwòrán, others
Diogo Jota

Oríṣun àwòrán, others
Ko ki n ṣe akọba fun ikọ Liverpool nikan sugbọn bii Diogo Jota ṣe farapa lo ṣe akọba lọpọpọ fun orilẹede Portugal.
Jota, ẹni ọdun mẹdọgbọn bọ sinu lasigbo orunkun lẹyin to farapa ninu ifẹsẹwọn to waye laarin ikọ Liverpool ati Ikọ Manchester City.
Ọpọ lo ti gbọ oerilẹede Portugal yoo fararan awọn ololufẹ ere bọọlu lagbaye nigba ti awọn agbabọọlu wọn bii Cristiano Ronaldo, Bernardo Silva ati Jota ba n ṣe bẹbẹ sugbọn ọrọ ba ibo miiran yoo pẹlu Jota

Oríṣun àwòrán, others
Sadio Mane
Balogun orilẹede Senegal naa ti farapa, eyi to ti han pe ko ni le kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye lorilẹede Qater. Mane, ẹni ti saaju ikọ orilẹede Senagal lati gba idije ilẹ adulawọ nigba ti wọn fiya jẹ Egypt.
Mane, ẹni to darapọ ikọ Bayern Munich lati ninu ikọ Liverpool lati ibẹrẹ saa yii.
Awọn yooku ni
Alexander Isak, omo orilẹede Sweden
Pedro Neto, omo orilẹede Portugal
Paulo Dybala, omo orilẹede Argentina
Kyle Walker, omo orilẹede England
Raphael Varane, omo orilẹede France
Kalvin Phillips, omo orilẹede England
Angel Di Maria, omo orilẹede Argentina















