Ṣé lóòtọ́ ni àwọn jàndùkú kọlu Atiku àti ikọ̀ ìpolongo rẹ̀ ní Borno?

Oríṣun àwòrán, AFP
Iroyin to n lọ ni pe awọn ọdọ kan kọlu awọn ọkọ oludije sipo aarẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar nipinlẹ Borno.
Ikọlu naa waye lasiko ti awọn ọkọ̀ naa n lọ si gbagede Ramat Square nilu Maiduguri, lati ba awọn alatilyin rẹ sọrọ.
Niṣe ni wọn ba awọn ọkọ naa jẹ, ti wọn si fọ gilaasi awọn kan.
Iroyin sọ pe o to aadọrin eeyan to farapa nibi ikọlu ọhun.
Ninu fidio kan to n lọ kaakiri lori ayelujara, ọpọlọpọ awọn ọkọ ipolongo Atiku ni wọn ba jẹ.
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa.
Ẹgbẹ naa sọ pe awọn janduku ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣe ijọba lọwọ nipinlẹ Borno lo wa lẹyin ikọlu naa.

Oríṣun àwòrán, @PDP
Ṣugbọn ijọba ipinlẹ naa sọ pe irọ ni.
Agbẹnusọ wọn, Isa Gusau sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ PDP funra wọn lo pete ikọlu naa.
Eyi kii ṣe igba akọkọ ti iroyin jade pe awọn janduku kọlu ikọ ipolongo oloṣelu ni Naijiria.
Ọpọ igba si ni dukia ati ẹmi awọn eeyan ma n ṣofo sinu awọn ikọlu bẹẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ẹnikẹni ko kọlu Atiku Abubakar
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Borno ti sọ pe ayederu ni iroyin to ni awọn janduku kọlu awọn ọkọ ipolongo oludije ẹgbẹ PDP.
Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, ASP Kamilu Shatambaya sọ fun awọn akọroyin pe gbọyi-sọyi iroyin lasan ni pe wọn kọlu ikọ ipolongo Atiku.
“Awọn oṣiṣẹ alaabo wa pẹlu Atiku Abubakar nigba to lọ si aafin Shehu ilu Borno, ati nigba to lọ si gbagede Ramat.
“Koda, kọmisanna ọlọpaa wa nibi eto naa lati ri i daju pe o lọ lai si wahala kankan.”
ASP Shatambaya sọ pe awọn tun lọ kaakiri awọn ileewosan lati wo boya eeyan mẹrinlelaadọrin ti wọn lo farapa wa nibẹ, amọ awọn ko ri ẹnikẹni.
Ṣugbọn o, o ni awọn mu ọkunrin kan, Danladi Abbas nitori pe o n gbiyanju lati sọ òkúta lu awọn ọkọ to ba Atiku rin loju ọna wọn si papakọ ọkọ ofurufu ilu Maiduguri.












