U.S Midterm Elections: Buhari kí àwọn ọmọ Naijiria tó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò ilẹ̀ Amẹrika kú oríire

US Midterm Elections

Oríṣun àwòrán, Abike Dabiri-Erewa

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ki awọn ọmọ Naijiria mẹjọ ti wọn kopa, ti wọn si tun jawe olubori ninu eto idibo ilẹ Amẹrika ti wọn ṣẹṣẹ ṣe tan.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Buhari, Femi Adesina fi lede, o ni awọn ọmọ Naijiria ti wọn dije du ipo aṣojuṣofin ni ipinlẹ Georgia lo jawe olubori.

Orukọ awọm eeyan naa ni Segun Adeyina, Gabe Okoye, Solomon Adesanya, Tish Naghise, ati Phil Olaleye.

Beẹ naa ni Carol Kazeem bori nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Pennsylvania ni District 159.

Wọn dibo yan Esther Agbaje lẹẹkeji ni ipinlẹ Minnesota ni District 59B, nigba ti wọn dibo yan Oye Owolewa lẹẹkeji gẹgẹ bii aṣojuṣofin ipinlẹ Washington D.C.

Aarẹ Buhari, ninu atẹjade naa gbadura fun awọn eeyan ọhun pe akoko wọn yoo to awọn araalu lara.

O tun dupẹ lọwọ wọn fun ifọwọsowọpọ wọn pẹlu ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere.

Buhari ni oun yoo tẹsiwaju lati maa ṣatilẹyin fun awọn ọmọ Naijiria rere to n gbe orukọ orilẹ-ede wọn ga nilẹ okeere.