Àwọn jàndùkú dáná sun ọ́fíìsì INEC tó wà nípìnlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, Amebo NG
Inu iyalẹnu nla l'awọn araalu Abẹokuta ati ipinlẹ Ogun lapapọ wa, lori bi awọn janduku kan tẹnikẹni ko tii mọ ṣe yawọ ọfiisi ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission, INEC ti ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Abẹokuta, eyi to wa lagbegbe Iyana-Mortuary, ti wọn si dana sun un.
Iroyin sọ pe oru mọju Ọjọbọ, ọjọ̀ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ni awọn janduku naa yawọ ọfiisi INEC yii, ti wọn si ju ina si i.
Wọn ni ṣe l’awọn janduku naa ko burẹdi lọpọ yanturu, ti wọn si da bẹntiroolu sinu ẹ, ko to di pe wọn ṣa ina si i, ti wọn si bẹrẹ sii juu sinu ọgba ajọ INEC yii.
Ọna ẹyin la gbọ pe wọn gba lati maa ju burẹẹdi ti wọn ti fina si naa wọle sinu ọgba ọhun, to si ṣe bẹrẹ si jo ọfiisi yii lati ọwọ ẹyin.

Oríṣun àwòrán, Amebo NG
Ọkan lara awọn ọlọdẹ inu ọgba INEC, Azeez Hamzat la gbọ pe o ta ileeṣẹ ọlọpaa ti ẹkun Ibara lolobo wi pe awọn tọọgi ti wọnu ọgba naa, wọn si ti n dana sun ọfiisi wọn.
Loju ẹsẹ ti wọn sọ pe iroyin naa ti tẹ awọn ọlọpaa lọwọ, ni wọn ti gbera lọ sibẹ. Awọn si ni wọn pe awọn oṣiṣẹ panapana.
A gbọ pe ṣaaju ki awọn ọlọpaa too debẹẹ, awọn janduku naa ti salọ, ti ko si si ẹni to le sọ iru eeyan ti wọn jẹ, tabi mọ ẹni to ran wọn niṣẹ.
Alaga INEC nipinlẹ Ogun kọmiinu

Oríṣun àwòrán, Amebo NG

Oríṣun àwòrán, Amebo NG
Nigba to n kọminu lori iṣẹlẹ naa, alaga ajọ eleto idibo nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Niyi Ijalaye sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ fun oun nitori pe awọn ko mọ idi ti wọn fi dana sun ọfiisi ajọ INEC.
“Lotitọ ni pe wọn dana sun ọfiisi wa. Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn. Mi o tiẹ mọ ohun ti mo le sọ lee lori bayii, nitori pe ojiji lo ba mi. Aarin oru to ṣẹlẹ la ti pe awọn ọlọpaa ati awọn eleto aabo yooku lati ran wa lọwọ.
“Awọn panapana naa si dide lati pa ina yooku. Apa kan ọfiisi wa lo jọna. A ṣi maa ṣe ipade lonii, lati wa ọna abayọ si eto aabo ileeṣẹ wa.”
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni a ko tii ri alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ba sọrọ.
Ninu awọn ohun t’awọn eeyan n sọ lori iṣẹlẹ yii ni pe, o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn oloṣẹlu lo wa nidii bi awọn janduku ṣe lọ dana sun ọfiisi ajọ INEC ipinlẹ Ogun.












